11 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e sì ni Ṣámà ọmọ Ágéè tó jẹ́ Hárárì. Àwọn Filísínì kóra jọ sí Léhì, sórí ilẹ̀ kan tí ẹ̀wà lẹ́ńtìlì pọ̀ sí; àwọn èèyàn náà sì sá nítorí àwọn Filísínì. 12 Àmọ́ ó dúró ní àárín ilẹ̀ náà, kò jẹ́ kí wọ́n gbà á, ó sì ń pa àwọn Filísínì náà, tó fi jẹ́ pé Jèhófà mú kí ìṣẹ́gun+ ńlá wáyé.