-
2 Sámúẹ́lì 19:15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Nígbà tí Ọba ń pa dà bọ̀, ó dé Jọ́dánì, àwọn èèyàn Júdà sì wá sí Gílígálì+ láti pàdé ọba, kí wọ́n lè mú un sọdá Jọ́dánì.
-
-
2 Sámúẹ́lì 19:41, 42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
41 Ìgbà náà ni gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí àwọn arákùnrin wa, àwọn ọkùnrin Júdà fi jí ọ gbé, tí wọ́n sì mú ọba àti agbo ilé rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin Dáfídì+ sọdá Jọ́dánì?” 42 Gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà dá àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì lóhùn pé: “Nítorí pé ìbátan wa+ ni ọba. Kí ló wá ń bí yín nínú lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé a jẹ oúnjẹ kankan sí ọba lọ́rùn ni, àbí ṣé ó fún wa lẹ́bùn ni?”
-