17 Torí náà, wọ́n gbé Àpótí Jèhófà wọlé, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ nínú àgọ́ tí Dáfídì pa fún un.+ Lẹ́yìn náà, Dáfídì rú àwọn ẹbọ sísun+ àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ níwájú Jèhófà.+
16 Dáfídì wá sọ fún àwọn olórí ọmọ Léfì pé kí wọ́n yan àwọn arákùnrin wọn tó jẹ́ akọrin láti máa fi ayọ̀ kọrin, kí wọ́n máa lo àwọn ohun ìkọrin, ìyẹn àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ pẹ̀lú síńbálì.*+