6 “‘Ní ti ẹni tó bá tọ àwọn abẹ́mìílò+ lọ àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́+ kó lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ó dájú pé màá bínú sí onítọ̀hún,* màá sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+
7 Níkẹyìn, Sọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá mi wá obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò,+ màá lọ wádìí lọ́wọ́ rẹ̀.” Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó! Obìnrin kan tí ó jẹ́ abẹ́mìílò wà ní Ẹ́ń-dórì.”+