18 Ni Ásà bá kó gbogbo fàdákà àti wúrà tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ibi ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ibi ìṣúra ilé ọba, ó sì kó wọn fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ọba Ásà wá fi wọ́n ránṣẹ́ sí Bẹni-hádádì ọmọ Tábúrímónì ọmọ Hésíónì, ọba Síríà,+ tó ń gbé ní Damásíkù, ó sọ pé: