ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 14:1-6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Ní ọdún kejì Jèhóáṣì+ ọmọ Jèhóáhásì ọba Ísírẹ́lì, Amasááyà ọmọ Jèhóáṣì ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jèhóádínì láti Jerúsálẹ́mù.+ 3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, àmọ́ kì í ṣe bíi ti Dáfídì+ baba ńlá rẹ̀. Gbogbo ohun tí Jèhóáṣì bàbá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.+ 4 Àmọ́ kò mú àwọn ibi gíga kúrò,+ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín ní àwọn ibi gíga.+ 5 Nígbà tí ìjọba rẹ̀ ti fìdí múlẹ̀ dáadáa, ó pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n pa bàbá rẹ̀ ọba.+ 6 Àmọ́ kò pa ọmọ àwọn apààyàn náà, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Jèhófà tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Òfin Mósè, pé: “Kí a má pa àwọn bàbá nítorí àwọn ọmọ wọn, kí a má sì pa àwọn ọmọ nítorí àwọn bàbá wọn; ṣùgbọ́n kí a pa kálukú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́