ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kọ́ríńtì 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kọ́ríńtì

      • Ó fún wọn níṣìírí láti máa fúnni (1-15)

        • Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú (7)

2 Kọ́ríńtì 9:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 15:26; 1Kọ 16:1; 2Kọ 9:12

2 Kọ́ríńtì 9:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 11:24; 19:17; 22:9; Onw 11:1; Lk 6:38

2 Kọ́ríńtì 9:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àìfẹ́ṣe.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:7, 10
  • +Ẹk 22:29; Owe 11:25; Iṣe 20:35; Heb 13:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 55

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 196

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2013, ojú ìwé 13

    12/1/2012, ojú ìwé 5

    11/1/1998, ojú ìwé 26

    12/1/1992, ojú ìwé 15

    1/15/1992, ojú ìwé 14-15, 18-19

2 Kọ́ríńtì 9:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 28:27; Mal 3:10; Flp 4:18, 19

2 Kọ́ríńtì 9:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fàlàlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 112:9

2 Kọ́ríńtì 9:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 210-212

2 Kọ́ríńtì 9:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 15:26, 27; 2Kọ 8:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 210-213

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2000, ojú ìwé 11-12

2 Kọ́ríńtì 9:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 5:16; Heb 13:16; Jem 1:27; 1Jo 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 210-212

2 Kọ́ríńtì 9:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 210-212, 216

2 Kọ́ríńtì 9:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 2 2017 ojú ìwé 4

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2016, ojú ìwé 9-10

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2015, ojú ìwé 14

    12/1/1993, ojú ìwé 28

    1/15/1992, ojú ìwé 19

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 210-212

Àwọn míì

2 Kọ́r. 9:1Ro 15:26; 1Kọ 16:1; 2Kọ 9:12
2 Kọ́r. 9:6Owe 11:24; 19:17; 22:9; Onw 11:1; Lk 6:38
2 Kọ́r. 9:7Di 15:7, 10
2 Kọ́r. 9:7Ẹk 22:29; Owe 11:25; Iṣe 20:35; Heb 13:16
2 Kọ́r. 9:8Owe 28:27; Mal 3:10; Flp 4:18, 19
2 Kọ́r. 9:9Sm 112:9
2 Kọ́r. 9:12Ro 15:26, 27; 2Kọ 8:14
2 Kọ́r. 9:13Mt 5:16; Heb 13:16; Jem 1:27; 1Jo 3:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kọ́ríńtì 9:1-15

Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì

9 Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó wà fún àwọn ẹni mímọ́,+ kò pọn dandan kí n kọ̀wé sí yín, 2 torí mo mọ bó ṣe ń yá yín lára, mo sì fi ń yangàn lójú àwọn ará Makedóníà, pé ó ti pé ọdún kan báyìí tí Ákáyà ti múra tán, ìtara yín sì ti mú kí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn gbára dì. 3 Àmọ́ mò ń rán àwọn arákùnrin náà sí yín, kí gbogbo bí a ṣe ń fi yín yangàn má bàa já sí asán nínú ọ̀ràn yìí, kí ẹ sì lè múra tán lóòótọ́, bí mo ṣe sọ pé ẹ máa ṣe. 4 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, tí àwọn ará Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì rí i pé ẹ ò múra sílẹ̀, ìtìjú á bá wa, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ẹ̀yin, torí pé a fọkàn tán yín. 5 Nítorí náà, mo wò ó pé ó ṣe pàtàkì láti fún àwọn arákùnrin náà ní ìṣírí pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ yín ṣáájú àkókò, kí wọ́n sì múra ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣèlérí sílẹ̀, kí èyí lè wà nílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí èèyàn fipá gbà.

6 Àmọ́ ní ti èyí, ẹni tó bá ń fúnrúgbìn díẹ̀ máa kórè díẹ̀, ẹni tó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu máa kórè yanturu.+ 7 Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe,*+ nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.+

8 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run lè mú kí gbogbo inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ pọ̀ gidigidi fún yín, kí ẹ lè máa ní ànító ohun gbogbo nígbà gbogbo, kí ẹ sì tún ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ fún iṣẹ́ rere gbogbo.+ 9 (Bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Ó ti pín nǹkan fún àwọn èèyàn káàkiri,* ó ti fún àwọn aláìní. Òdodo rẹ̀ wà títí láé.”+ 10 Ẹni tó ń pèsè irúgbìn lọ́pọ̀ yanturu fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún jíjẹ máa pèsè irúgbìn, ó máa sọ ọ́ di púpọ̀ fún yín láti gbìn, á sì mú èso òdodo yín pọ̀ sí i.) 11 Ọlọ́run ti bù kún yín ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ lè máa fúnni lóríṣiríṣi ọ̀nà, èyí sì ń mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; 12 nítorí iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe fún àwọn èèyàn kì í ṣe láti fún àwọn ẹni mímọ́ ní ohun tí wọ́n nílò nìkan,+ ó tún máa mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run. 13 Ohun tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìrànwọ́ yìí ń ṣe jẹ́ ẹ̀rí, èyí sì ń mú kí wọ́n máa yin Ọlọ́run lógo torí pé ẹ̀ ń ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Kristi, bí ẹ ṣe kéde fún àwọn èèyàn, tí ẹ sì jẹ́ ọ̀làwọ́ nínú ọrẹ tí ẹ̀ ń ṣe fún wọn àti fún gbogbo èèyàn.+ 14 Wọ́n fi ìfẹ́ hàn sí yín bí wọ́n ṣe ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ fún yín, torí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ tó wà lórí yín.

15 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí kò ṣeé ṣàpèjúwe.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́