ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es18 ojú ìwé 7-17
  • January

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • January
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Monday, January 1
  • Tuesday, January 2
  • Wednesday, January 3
  • Thursday, January 4
  • Friday, January 5
  • Saturday, January 6
  • Sunday, January 7
  • Monday, January 8
  • Tuesday, January 9
  • Wednesday, January 10
  • Thursday, January 11
  • Friday, January 12
  • Saturday, January 13
  • Sunday, January 14
  • Monday, January 15
  • Tuesday, January 16
  • Wednesday, January 17
  • Thursday, January 18
  • Friday, January 19
  • Saturday, January 20
  • Sunday, January 21
  • Monday, January 22
  • Tuesday, January 23
  • Wednesday, January 24
  • Thursday, January 25
  • Friday, January 26
  • Saturday, January 27
  • Sunday, January 28
  • Monday, January 29
  • Tuesday, January 30
  • Wednesday, January 31
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2018
es18 ojú ìwé 7-17

January

Monday, January 1

Máa ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́.​—Júúdà 3.

Ọmọbìnrin kan sáré lọ pàdé bàbá rẹ̀. Inú ẹ̀ dùn gan-an pé bàbá rẹ̀ togun dé ní ayọ̀ àti àlàáfíà. Ó ń jó, ó ń yọ̀, torí pé bàbá rẹ̀ ti ja àjàṣẹ́gun. Àmọ́, ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe àtohun tó sọ lẹ́yìn náà yà á lẹ́nu. Ó faṣọ ya mọ́ra ẹ̀ lọ́rùn, ó sì kígbe pé: “Págà, ọmọbìnrin mi! O ti mú mi tẹ̀ ba ní tòótọ́.” Ó wá sọ fún un pé òun ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan fún Jèhófà, ẹ̀jẹ́ náà sì máa yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà pátápátá. Ohun tí ẹ̀jẹ́ yẹn túmọ̀ sí ni pé ọmọbìnrin náà ò ní lọ́kọ, kò sì ní lọ́mọ láyé. Àmọ́, ojú ẹsẹ̀ ló sọ ohun kan tó dùn mọ́ bàbá ẹ̀ nínú, ó ní kó mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Ohun tó sọ yìí fi hàn pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì gbà pé ohun yòówù tí Jèhófà bá rí pó máa ṣòun láǹfààní ló máa ní kóun ṣe. (Oníd. 11:34-37) Nígbà tí bàbá rẹ̀ rí bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe lágbára tó, inú ẹ̀ dùn gan-an torí ó mọ̀ pé ohun tọ́mọ náà fẹ́ ṣe máa múnú Jèhófà dùn. Jẹ́fútà àti ọmọbìnrin rẹ̀ ò ṣiyè méjì kankan nípa Jèhófà àti ọ̀nà tó ń gbà ṣe nǹkan. Bí ò tiẹ̀ rọrùn fún wọn láti ṣe ohun tí Jèhófà ní kí wọ́n ṣe, síbẹ̀ wọ́n ṣègbọràn. Wọ́n fẹ́ rí ojúure Jèhófà, ohunkóhun téèyàn bá sì yááfì kó lè rójú rere Ọlọ́run tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. w16.04 1:1, 2

Tuesday, January 2

Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá. ​—Ják. 5:11.

Nígbà míì, ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mẹ́ńbà ìdílé rẹ kan lè sọ ohun kan tó dùn ẹ́ gan-an. O sì lè máa ṣàìsàn tó le koko tàbí kí èèyàn rẹ kan kú. Àmọ́, ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí wa, àpẹẹrẹ Jóòbù lè tù wá nínú. (Jóòbù 1:18, 19; 2:7, 9; 19:1-3) Jóòbù ò mọ ìdí tí onírúurú àjálù fi ń dé bá òun, àmọ́ kò bọ́hùn. Kí ló mú kó lè fara dà á? Ohun kan ni pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò sì fẹ́ ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí. (Jóòbù 1:1) Ohun míì ni pé Jóòbù ti pinnu pé ohun tí Jèhófà fẹ́ lòun á máa ṣe nígbà tó rọgbọ àti nígbà tí kò rọgbọ. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà tún jẹ́ kí Jóòbù rí bí agbára òun ṣe pọ̀ tó nígbà tó sọ fún un nípa àwọn ohun àgbàyanu tó dá. Èyí mú kó dá Jóòbù lójú pé tó bá tó àkókò lójú Jèhófà, á fòpin sí àjálù tó dé bá òun. (Jóòbù 42:1, 2) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. “Jèhófà tìkára rẹ̀ sì yí ipò òǹdè Jóòbù padà . . . Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí fún Jóòbù ní àfikún ohun gbogbo tí ó jẹ́ tirẹ̀ rí.” Jóòbù “darúgbó, ó sì kún tẹ́rùn-tẹ́rùn fún ọjọ́.”​—Jóòbù 42:10, 17. w16.04 2:11, 13

Wednesday, January 3

Ẹ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà. ​—Mát. 10:16.

Bá a ṣe lè jẹ́ “oníṣọ̀ọ́ra” ni pé ká máa ronú nípa ìṣòro tó lè yọjú lójijì. A gbọ́dọ̀ wà lójúfò táwọn èèyàn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, a ò ní sọ pé a fara mọ́ ohun tí ẹgbẹ́ òṣèlú kan ṣe tàbí pé a ò fara mọ́ ọn. Dípò ká máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọba èèyàn ṣe fẹ́ yanjú ìṣòro aráyé, á dáa ká kúkú fi bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa yanjú ìṣòro náà hàn wọ́n nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, táwọn èèyàn bá fẹ́ mọ èrò wa nípa ọ̀rọ̀ ìṣẹ́yún tàbí bí ọkùnrin ṣe ń fẹ́ ọkùnrin tí obìnrin sì ń fẹ́ obìnrin, ṣe ni ká sọ ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, ká sì sọ bí àwa náà ṣe ń fi í sílò nínú ìgbésí ayé wa. Bí ẹnì kan bá sọ pé ó yẹ kí ìjọba fagi lé àwọn òfin kan tàbí kí wọ́n ṣàtúnṣe sí i, a ò ní sọ pé ó dáa tàbí kò dáa, a ò sì ní gbìyànjú láti yí onítọ̀hún lérò pa dà. w16.04 4:8, 9

Thursday, January 4

Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn.​—Mát. 28:19.

A gbọ́dọ̀ máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ká máa batisí wọn, ká sì máa kọ́ wọn. Àmọ́, kí lohun àkọ́kọ́ tá a gbọ́dọ̀ ṣe? Jésù sọ pé: “Ẹ lọ”! Nígbà tí ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan ń sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ tí Jésù pa yìí, ó ní: “Iṣẹ́ gbogbo onígbàgbọ́ ni pé kí wọ́n ‘lọ,’ yálà sójú pópó tàbí kí wọ́n ré kọjá òkun.” (Mát. 10:7; Lúùkù 10:3) Ṣé ohun tó ń sọ ni pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa dá ṣe iṣẹ́ náà bó ṣe wù ú àbí ó fẹ́ kí wọ́n pawọ́ pọ̀ wàásù ìhìn rere náà kí wọ́n sì wà létòletò? Níwọ̀n bí ẹnì kan ṣoṣo ò ti ní lè wàásù fún “gbogbo orílẹ̀-èdè,” iṣẹ́ yìí máa gba ìsapá ọ̀pọ̀ èèyàn. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wá di “apẹja ènìyàn.” (Mát. 4:18-22) Ẹja pípa tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ níbí kì í ṣe ti apẹja kan tó ń lo ìdẹ àti ìwọ̀ fi pẹja, táá wá jókòó títí tí ìwọ̀ á fi gbé ẹja náà. Àwọ̀n ni wọ́n á fi mú àwọn ẹja tí Jésù ń sọ. Iṣẹ́ tó gba agbára, tó sì gba pé kí ọ̀pọ̀ èèyàn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ni.​—Lúùkù 5:1-11. w16.05 2:3, 4

Friday, January 5

Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.​—Òwe 3:5,  6.

Ká lè túbọ̀ máa mọ èrò Jèhófà, a gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìdákẹ́kọ̀ọ́. Tá a bá ń ka Bíbélì tàbí tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ká máa bi ara wa pé, ‘Kí lohun tí mo kà yìí jẹ́ kí n mọ̀ nípa Jèhófà, kí ló jẹ́ kí n mọ̀ nípa èrò rẹ̀ àtàwọn ìlànà rẹ̀?’ Ó yẹ ká ní irú èrò tí onísáàmù náà Dáfídì ní, ó kọ ọ́ lórin pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ. Mú mi rìn nínú òtítọ́ rẹ, kí o sì kọ́ mi, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi. Mo ti ní ìrètí nínú rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sm. 25:4, 5) Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ẹsẹ Bíbélì kan tó o kà, o lè bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè fi ibi tí mo kà yìí sílò nínú ìdílé mi? Ibo ni mo ti lè fi í sílò? Ṣé nínú ilé ni àbí níléèwé, níbiiṣẹ́ àbí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?’ Tá a bá ti mọ àwọn ibi tá a ti lè lò ó, á rọrùn fún wa láti lè fòye mọ bá a ṣe máa fi í sílò. w16.05 3:9,11

Saturday, January 6

Alábòójútó ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn.​—1 Tím. 3:2.

Ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká rí i pé ohun tí Jèhófà ní káwọn tó fẹ́ di alàgbà kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ kọjá ṣeréṣeré. (1 Tím. 3:2-7) Jèhófà retí pé kí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere kí wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú ìjọ “èyí tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ òun fúnra rẹ̀ rà.” (Ìṣe 20:28) Jèhófà fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn alàgbà tá a fi wé olùṣọ́ àgùntàn á bójú tó wa lọ́nà tó dára. (Aísá. 32:1, 2) Àwọn ohun tí Jèhófà ní káwọn tó fẹ́ di alàgbà kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Kódà, gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí torí pé èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ohun tó wà níbẹ̀ ni Jèhófà ń retí pé kí gbogbo Kristẹni kúnjú ìwọ̀n rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, gbogbo Kristẹni ló yẹ kó yè kooro ní èrò inú kí wọ́n sì máa fòye báni lò. (Fílí. 4:5; 1 Pét. 4:7) Bí àwọn alàgbà ṣe ń fi “àpẹẹrẹ” tó dáa lélẹ̀ “fún agbo,” àá máa rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára wọn, àá sì lè máa “fara wé ìgbàgbọ́ wọn.”​—1 Pét. 5:3; Héb. 13:7. w16.05 5:8-10

Sunday, January 7

Ju gbogbo ohun mìíràn tí a ní láti ṣọ́, fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ. ​—Òwe 4:23.

Àwọn nǹkan tó lè mú kí ọkàn wa le wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún? Lára ẹ̀ ni ìgbéraga, kéèyàn máa dẹ́ṣẹ̀ tàbí kéèyàn jẹ́ aláìnígbàgbọ́. Àwọn ìwà yìí lè sọni di aláìgbọràn, ó sì lè mú kéèyàn ya ọlọ̀tẹ̀. (Dán. 5:1, 20; Héb. 3:13, 18, 19) Àpẹẹrẹ ẹnì kan tó lẹ́mìí ìgbéraga ni Ùsáyà Ọba Júdà. (2 Kíró. 26:3-5, 16-21) Níbẹ̀rẹ̀, Bíbélì ròyìn pé Ùsáyà ṣe “ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,” àti pé ó ‘ń bá a lọ ní wíwá Ọlọ́run.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ló fún Ùsáyà lágbára, Bíbélì sọ pé “gbàrà tí ó di alágbára, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera.” Ìgbéraga náà wọ̀ ọ́ lẹ́wù débi pé ó lọ sí tẹ́ńpìlì láti sun tùràrí. Ìkọjá ayé gbáà, iṣẹ́ tó jẹ́ pé àwọn àlùfáà ọmọ Áárónì nìkan ló máa ń ṣe é. Nígbà táwọn àlùfáà sì sọ fún un pé ohun tó ń ṣe kò dáa, ńṣe ni Ùsáyà gbaná jẹ! Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí? Ìtìjú ló bá kúrò níbẹ̀, Ọlọ́run sọ ọ́ di adẹ́tẹ̀, bó sì ṣe wà nìyẹn tó fi kú. (Òwe 16:18) Tá ò bá kíyè sára, tá a jẹ́ kí ìgbéraga wọ̀ wá lẹ́wù, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í “ro ara [wa] ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ,” débi pé a ò ní gba ìbáwí tí wọ́n bá fún wa látinú Bíbélì.​—Róòmù 12:3; Òwe 29:1. w16.06 2:3, 4

Monday, January 8

[Ẹ máa fara dà á] fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìfẹ́.​—Éfé. 4:2.

Ojú wo lo fi máa ń wo àwọn Kristẹni tó wá láti ẹ̀yà míì? Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, ìmúra wọn, ìwà wọn àti oúnjẹ wọn lè yàtọ̀ sí tìẹ. Ṣé o máa ń fọgbọ́n yẹ̀ wọ́n sílẹ̀, tó fi jẹ́ pé àwọn tí ẹ jọ mọwọ́ ara yín nìkan lo máa ń bá ṣe? Kí lo máa ṣe tó bá jẹ́ pé àwọn alábòójútó tí ètò Ọlọ́run yàn sípò kéré sí ẹ lọ́jọ́ orí tàbí tí wọ́n bá wá láti ẹ̀yà míì tàbí tí àwọ̀ wọn bá yàtọ̀ sí tìẹ? Kí ni wàá ṣe tí wọ́n bá jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ rẹ tàbí ní àyíká yín tàbí tí wọn bá wà nínú ìgbìmọ̀ ẹ̀ka? Ṣé wàá jẹ́ kí irú àwọn ìyàtọ̀ bẹ́ẹ̀ ba ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà jẹ́? Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní fàyè gba èrò tí kò tọ́ yìí? Ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù tó jẹ́ ìlú tí onírúurú ẹ̀yà ń gbé lè ràn wá lọ́wọ́. (Éfé. 4:1-3) Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ mẹ́nu kan àwọn ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀, ìwà tútù, ìpamọ́ra àti ìfẹ́. A lè fi àwọn ànímọ́ yìí wé àwọn òpó tó mú ilé ró. w16.06 3:17, 18

Tuesday, January 9

Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò. ​—Lúùkù 12:15.

Sátánì ò fẹ́ ká sin Jèhófà, Ọrọ̀ ló fẹ́ ká máa lé. (Mát. 6:24) Àwọn tó ń fi gbogbo ìgbésí ayé wọn kó ohun ìní jọ kì í láyọ̀, ìgbésí ayé wọn kì í sì í nítumọ̀ torí pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. Èyí tó burú jù níbẹ̀ ni pé ìjọsìn Ọlọ́run lè má ṣe pàtàkì sí wọn mọ́, wọ́n sì lè ní ẹ̀dùn ọkàn àti ìjákulẹ̀. (1 Tím. 6:9, 10; Ìṣí. 3:17) Ohun tí Jésù sọ nínú àkàwé akárúgbìn nìyẹn. Nígbà tí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run bọ́ “sáàárín àwọn ẹ̀gún . . . , ìfẹ́-ọkàn fún àwọn nǹkan yòókù gbógun wọlé, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ó sì di aláìléso.” (Máàkù 4:14, 18, 19) Bí àwa náà ṣe ń sún mọ́ òpin ètò àwọn nǹkan yìí, kì í ṣe ìsinsìnyí ló yẹ ká máa to ọrọ̀ jọ pelemọ fún ara wa. Kò yẹ ká máa retí pé èyíkéyìí lára dúkìá wa máa la ìpọ́njú ńlá já bó ti wù kí nǹkan ọ̀hún ṣeyebíye tó.​—Òwe 11:4; Mát. 24:21, 22. w16.07 1:5, 6

Wednesday, January 10

Gbogbo wa ti gba . . . inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí. ​—Jòh. 1:16.

Ọkùnrin kan tó ní ọgbà àjàrà lọ sí ọjà láti wá àwọn lébìrà tàbí àwọn òṣìṣẹ́ tó máa ṣiṣẹ́ lóko rẹ̀. Òun àtàwọn ọkùnrin tó rí jọ ṣàdéhùn iye tí wọ́n máa gbà, àwọn òṣìṣẹ́ náà sì lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Àmọ́, ọkùnrin náà ṣì nílò àwọn òṣìṣẹ́ sí i, torí náà jálẹ̀ ọjọ́ náà ló fi ń pààrà ọjà láti wá àwọn òṣìṣẹ́, ó sì ń bá àwọn tó rí ṣàdéhùn iye tí wọ́n máa gbà, títí kan àwọn tó gbà síṣẹ́ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Nígbà tí iṣẹ́ parí, ọkùnrin náà pe àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ jọ, ó sì fún wọn ní iye tó bá wọn ṣàdéhùn, ó wá bọ́ sí pé iye kan náà ló fún gbogbo wọn, látorí àwọn tó ti ń fara ṣiṣẹ́ látàárọ̀ àtàwọn tí kò ṣe ju wákàtí kan lọ. Nígbà táwọn tó ti wà lóko látàárọ̀ gbọ́ pé iye kan náà ló fún wọn, ṣe ni wọ́n fárígá. Ọkùnrin náà wá bi wọ́n pé: ‘Ṣebí iye tá a jọ ṣàdéhùn ni mo fún yín, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣé mi ò lẹ́tọ̀ọ́ láti fún àwọn tó bá mi ṣiṣẹ́ ni iye tó wù mí ni? Kí ló dé tí ẹ̀ ń jowú torí pé mò ń ṣoore fáwọn èèyàn?’ (Mát. 20:​1-15) Àkàwé tí Jésù ṣe yìí rán wa létí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jèhófà tí Bíbélì sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ìyẹn “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.”​—2 Kọ́r. 6:1. w16.07 3:1, 2

Thursday, January 11

Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun. . . . Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.​—Ìṣí. 21:5.

Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, pàápàá bí òpin ṣe ń sún mọ́lé! (Máàkù 13:10) Kò sí àní-àní, ìhìn rere ni inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà jẹ́. Ká máa fi kókó yìí sọ́kàn nígbà tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn. Ká má sì gbàgbé pé ká bàa lè fògo fún Jèhófà la ṣe ń wàásù. Nípa bẹ́ẹ̀, àá jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé inú rere Jèhófà ló máa mú ká gbádùn àwọn ìbùkún àgbàyanu nínú ayé tuntun. Tá a bá ń wàásù fáwọn èèyàn, ká máa ṣàlàyé fún wọn pé aráyé máa jàǹfààní lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n á jadùn gbogbo oore tí ẹbọ ìràpadà ní, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n á di pípé. Bíbélì sọ pé: “A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 8:21) Inú rere àrà ọ̀tọ̀ tí Jèhófà ní sí wa láá jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀. w16.07 4:17-19

Friday, January 12

Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n kí aya pẹ̀lú máa ṣe bákan náà fún ọkọ rẹ̀. ​—1 Kọ́r. 7:3.

Lóòótọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya, Bíbélì ò ṣòfin nípa onírúurú ọ̀nà tí tọkọtaya lè gbà ṣeré ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ sì ni kò díwọ̀n bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é tó, síbẹ̀ ó rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa fìfẹ́ hàn síra wọn. (Orin Sól. 1:2; 2:6) Bíbélì sọ pé kí tọkọtaya máa bá ara wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Torí pé ẹ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ara yín, ẹ ò ní gba ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun láyé láti wọ àárín yín. Àwọn kan ti jẹ́ kí ìwòkuwò da ìgbéyàwó wọn rú. Ẹ má ṣe fàyè gba irú ẹ̀, ẹ má sì jẹ́ kí ọkàn yín máa fà sẹ́ni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya yín. Kódà, kò yẹ ká ṣe ohunkóhun tó máa jẹ́ kó dà bíi pé à ń fa ojú ẹlòmíì mọ́ra, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká máa bá ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa tage. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò fi hàn pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ̀. Tá a bá ń rántí pé arínúróde ni Jèhófà, a ò ní ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, àá sì tipa bẹ́ẹ̀ máa múnú rẹ̀ dùn.​—Mát. 5:​27, 28; Héb. 4:13. w16.08 2:7-9

Saturday, January 13

Àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ [Ọlọ́run].​—Kól. 1:9.

Táwọn ará Kólósè bá ní ìmọ̀ pípéye, wọ́n á lè “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún.” Èyí á mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa “bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo,” ní pàtàkì jù lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Kól. 1:10) Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé tá a bá fẹ́ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Ó sì ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ káwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ká tó lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwa náà gbọ́dọ̀ ti rí àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí fi hàn pé àwa náà gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Tí àwọn tí mo wàásù fún bá sọ ohun kan tó yàtọ̀ sí ohun tó wà nínú Bíbélì tàbí tí wọ́n béèrè ìbéèré tó le lọ́wọ́ mi, ṣé mo lè fi Bíbélì dá wọn lóhùn?’ Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa sọ àwọn àǹfààní tá à ń rí látinú bá a ṣe ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fáwọn èèyàn, èyí á mú kó yá wọn lára láti túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. w16.08 4:3, 4

Sunday, January 14

Àwa ní gídígbò kan . . . lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.​—Éfé. 6:12.

Ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jẹ́ kí “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” nínú ayé yìí kó èèràn ràn wá. Lára wọn ni àwọn ẹ̀kọ́ èké, àwọn ẹ̀kọ́ tó dá lórí èrò àwọn èèyàn aláìpé àtàwọn ìwàkiwà bí ìṣekúṣe, sìgá tàbí igbó mímu, ọtí àmujù àti lílo oògùn olóró. Yàtọ̀ sáwọn nǹkan yìí, a tún ń bá àìpé wa àti ìrẹ̀wẹ̀sì wọ̀yá ìjà, a ò sì gbọ́dọ̀ dẹwọ́. (2 Kọ́r. 10:3-6; Kól. 3:5-9) Ṣé a lè borí àwọn ọ̀tá alágbára yìí? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ a gbọ́dọ̀ jà fitafita. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé ohun tóun ṣe, ó lo àpẹẹrẹ àwọn tó ń kan ẹ̀ṣẹ́, ó ní: “Bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́.” (1 Kọ́r. 9:26) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa jà fitafita láti borí àwọn ọ̀tá wa bíi tàwọn tó ń kànṣẹ́. Jèhófà ti kọ́ wa láwọn nǹkan tá a lè ṣe, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́. Ó ń tọ́ wa sọ́nà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà ló ń ràn wá lọ́wọ́ nípasẹ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa, ìpàdé ìjọ àtàwọn àpéjọ wa. Ìbéèrè náà ni pé, ṣó ò ń fi àwọn ẹ̀kọ́ náà sílò? w16.09 2:2, 3

Monday, January 15

Kristi pàápàá kò ṣe bí ó ti wu ara rẹ̀.​—Róòmù 15:3.

Jésù máa ń fi ire àwọn míì ṣáájú tiẹ̀, ó mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kóun máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tóun bá máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àwa náà lè ṣe bíi ti Jésù, ká má ṣe máa wọ àwọn aṣọ tá a nífẹ̀ẹ́ sí àmọ́ tí kò ní jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ìwàásù wa. (Róòmù 15:2) Àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ fi ìlànà Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ wọn. Lára ohun tí wọ́n ní láti ṣe ni pé kí wọ́n rí i dájú pé àwọn ọmọ wọn àtàwọn alára ń múnú Jèhófà dùn nípa mímúra lọ́nà tó bójú mu. (Òwe 22:6; 27:11) Tẹ́yin òbí bá ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ọmọ yín, tẹ́ ẹ sì ń fìfẹ́ tọ́ wọn sọ́nà, ẹ̀ẹ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run. Á dáa kẹ́ ẹ kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ra aṣọ tó bójú mu àti ibi tí wọ́n ti lè rí irú aṣọ bẹ́ẹ̀ rà. Kẹ́ ẹ kọ́ wọn pé kì í ṣe ohun tó wù wọ́n nìkan ni kí wọ́n rà, àmọ́ kí wọ́n ra ohun táá jẹ́ kí wọ́n lè fira wọn hàn bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. w16.09 3:13, 14

Tuesday, January 16

Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan kò ga ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.​—Lúùkù 6:40.

Jésù mọ bá a ṣe ń kọ́ni dáadáa, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì máa ń wọni lọ́kàn torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. (Lúùkù 24:32; Jòh. 7:46) Irú ìfẹ́ yìí náà ló máa mú kí ọ̀rọ̀ àwọn òbí wọ àwọn ọmọ wọn lọ́kàn. (Diu. 6:5-8; Lúùkù 6:45) Torí náà, ẹ̀yin òbí, ẹ bá Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde ètò Jèhófà dọ́rẹ̀ẹ́ dáadáa. Ẹ máa kíyè sí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá, kẹ́ ẹ sì máa lo àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá. (Mát. 6:26, 28) Tẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, òye tẹ́ ẹ ní á túbọ̀ jinlẹ̀, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ mọyì Jèhófà, ìyẹn á sì jẹ́ kẹ́ ẹ lóhun púpọ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ yín. Tí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá wà lọ́kàn ẹ̀yìn òbí digbí, ńṣe láá máa yá yín lára láti sọ ọ́ fáwọn ọmọ yín. Torí náà, ẹ má fi mọ sígbà tẹ́ ẹ bá ń múra ìpàdé tàbí nígbà Ìjọsìn Ìdílé nìkan. Síbẹ̀, ẹ má fipá mú wọn, ẹ jẹ́ kó máa wù wọ́n láti sọ tọkàn wọn, kó máa wà lára ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ jọ ń sọ lójoojúmọ́. w16.09 5:6, 7

Wednesday, January 17

Kò sì sí ìkankan nínú wọn tí ó mọ bí a ti ń sọ èdè Júù. ​—Neh. 13:24.

Téèyàn bá lọ sìn nílẹ̀ àjèjì, àmọ́ tí kò gbédè ibẹ̀ dáadáa, ó lè ṣòro fún un láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì lè pa ìjọsìn rẹ̀ lára. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó ká Nehemáyà lára nígbà tó gbọ́ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ Júù kò gbọ́ èdè Hébérù. Àìgbédè àwọn ọmọ yẹn kò jẹ́ kí wọ́n lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn sì mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà yingin. (Neh. 8:2, 8) Àwọn òbí kan tó ń sìn nílẹ̀ àjèjì ti rí i pé ìfẹ́ táwọn ọmọ wọn ní fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti ń tutù. Kí nìdí? Ìdí ni pé tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ lédè àjèjì, ó lè má fi bẹ́ẹ̀ wọ̀ wá lọ́kàn bíi kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ lédè abínibí rẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá fi bẹ́ẹ̀ gbédè, ó lè jẹ́ kí nǹkan tètè sú wa, ó sì lè mú kí ìgbàgbọ́ wa jó rẹ̀yìn. Torí náà, bá a ṣe ń sìn lágbègbè tí wọ́n ti ń sọ èdè àjèjì, ó ṣe pàtàkì pé ká sa gbogbo ipá wa kí iná ìgbàgbọ́ wa má bàa jó rẹ̀yìn.​—Mát. 4:4. w16.10 2:4-6

Thursday, January 18

Ìgbàgbọ́ ni . . . ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.​—Héb. 11:1.

Ànímọ́ tó ṣe pàtàkì ni ìgbàgbọ́. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló nígbàgbọ́. (2 Tẹs. 3:2) Bó ti wù kó rí, Jèhófà ń fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń sìn ín ní “ìwọ̀n ìgbàgbọ́” tí wọ́n nílò. (Róòmù 12:3; Gál. 5:22) Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ mọyì ohun tí wọ́n ní. Jésù Kristi sọ pé Jèhófà ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nípasẹ̀ òun. (Jòh. 6:44, 65) Tá a bá nígbàgbọ́ nínú Jésù, àá rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ìyẹn á sì jẹ́ ká ní àjọṣe tó gún régé pẹ̀lú Jèhófà títí lọ gbére. (Róòmù 6:23) Ìbùkún ńlá mà nìyẹn o! Àmọ́, ṣé á lẹ́tọ̀ọ́ sí i? Rárá, ìdí ni pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá, ikú ló sì tọ́ sí wa. (Sm. 103:10) Àmọ́ Jèhófà rí i pé a ṣì lè ṣe ohun tó dáa. Torí bẹ́ẹ̀, ó fojúure hàn sí wa, ó sì mú ká tẹ́tí sí ìhìn rere. Ìyẹn ló mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù, a sì nírètí àtigbé títí láé nínú ayé tuntun.​—1 Jòh. 4:9, 10. w16.10 4:1, 2

Friday, January 19

[Pọ́ọ̀lù] fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀ ní ìṣírí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀.​—Ìṣe 20:2.

Pọ́ọ̀lù máa ń gbóríyìn fáwọn ará nínú àwọn lẹ́tà tó kọ. Òun àtàwọn mélòó kan lára wọn ti jọ rìnrìn-àjò fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ó sì dájú pé ó mọ kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, síbẹ̀ àwọn nǹkan rere tí wọ́n ṣe ló mẹ́nu bà. Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù sọ pé Tímótì jẹ́ ọmọ òun “olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti olùṣòtítọ́ nínú Olúwa,” ẹni tó máa fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ará. (1 Kọ́r. 4:17; Fílí. 2:19, 20) Àpọ́sítélì náà tún ròyìn Títù fún àwọn ará tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì pé ó jẹ́ “alájọpín pẹ̀lú [òun] àti alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ire” wọn. (2 Kọ́r. 8:23) Ó dájú pé inú Tímótì àti Títù máa dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa wọn. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fẹ̀mí ara wọn wewu bí wọ́n ṣe pa dà lọ sáwọn ìlú tí wọ́n ti ṣe inúnibíni sí wọn. Bí àpẹẹrẹ, láìka àtakò tó le tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kojú ní ìlú Lísírà, wọ́n pa dà síbẹ̀ kí wọ́n lè fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dọmọ ẹ̀yìn níṣìírí kí ìgbàgbọ́ wọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Ìṣe 14:19-22) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Éfésù, àwọn èèyàn ìlú náà kóra jọ wọ́n sì dá rúgúdù sílẹ̀, àmọ́ Pọ́ọ̀lù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà nílùú náà ní ìṣírí.​— Ìṣe 20:1. w16.11 1:10, 11

Saturday, January 20

Kí a . . . so yín pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.​—1 Kọ́r. 1:10.

Lónìí, Jèhófà ń bọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì ń darí wọn. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ni ó ń lò láti ṣe iṣẹ́ yìí, Kristi tó jẹ́ “orí ìjọ” ló sì ń darí wọn. (Mát. 24:45-47; Éfé. 5:23) Bíi ti ìgbìmọ̀ olùdarí ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ẹrú yìí gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, wọ́n sì fọwọ́ pàtàkì mú un. (1 Tẹs. 2:13) Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ máa pé jọ sípàdé déédéé. (Héb. 10:​24, 25) Ó tún sọ pé ìmọ̀ òtítọ́ tá a ní gbọ́dọ̀ ṣọ̀kan. Bíbélì sọ fún wa pé Ìjọba Ọlọ́run la gbọ́dọ̀ fi sípò àkọ́kọ́ ní ìgbésí ayé wa. (Mát. 6:33) Ìwé Mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ máa wàásù láti ilé dé ilé, ká sì máa kọ́ àwọn èèyàn láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí àti lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 5:42; 17:17; 20:20) Bíbélì sọ pé àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ mú kí ìjọ Ọlọ́run wà ní mímọ́. (1 Kọ́r. 5:1-5, 13; 1 Tím. 5:19-21) Jèhófà sì sọ pé gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ nípa tara àti nípa tẹ̀mí.​—2 Kọ́r. 7:1. w16.11 3:7, 8

Sunday, January 21

Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi.​—Ìṣí. 18:4.

Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní, Arákùnrin Charles Taze Russell àtàwọn yòókù rẹ̀ rí i kedere pé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ò kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ìdí nìyẹn táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà fi pinnu pé àwọn ò ní ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú gbogbo ìsìn tí wọ́n kà sí ìsìn èké. Kódà, nínú ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower tó jáde lóṣù November, 1879, wọ́n jẹ́ káyé mọ̀ pé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ làwọn rọ̀ mọ́. Wọ́n sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí tó bá sọ pé òun jẹ́ wúńdíá ìyàwó Kristi, àmọ́ tó wá ń ní àjọṣe pẹ̀lú ayé (ìyẹn ẹranko) tí ayé sì ń tì lẹ́yìn, kò sí orúkọ míì tá a lè pe irú ṣọ́ọ̀ṣì bẹ́ẹ̀ bí kò ṣe orúkọ tí Ìwé Mímọ́ pè é, orúkọ náà ni aṣẹ́wó ṣọ́ọ̀ṣì,” ìyẹn Bábílónì Ńlá. (Ìṣí. 17:​1, 2) Àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin mọ ohun tó yẹ káwọn ṣe. Wọ́n mọ̀ pé táwọn bá máa rí ojúure Ọlọ́run, àwọn ò gbọ́dọ̀ ti ìsìn èké lẹ́yìn lọ́nàkọnà. Torí náà, ọ̀pọ̀ lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló kọ lẹ́tà sáwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọn pé àwọn ò ṣe mọ́. w16.11 5:2, 3

Monday, January 22

Àwọn tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí [gbé èrò inú wọn ka] àwọn ohun ti ẹ̀mí.​—Róòmù 8:5.

Nígbà Ìrántí Ikú Jésù, a sábà máa ń ka Róòmù 8:15-17. Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣàlàyé bí àwọn ẹni àmì òróró ṣe máa ń mọ̀ pé Ọlọ́run ti yan àwọn, ó ní ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wọn. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró la dìídì darí orí Bíbélì yìí sí. Wọ́n gba “ẹ̀mí,” wọ́n sì ń ‘dúró de ìsọdọmọ, ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ẹran ara wọn nípasẹ̀ ìràpadà.’ (Róòmù 8:23) Lọ́jọ́ iwájú, wọ́n nírètí láti lọ sọ́run, wọ́n sì máa di ọmọ Ọlọ́run. Ohun tó mú kí èyí ṣeé ṣe ni pé, wọ́n ṣèrìbọmi, Ọlọ́run sì mú kí wọ́n jọlá ẹbọ ìràpadà náà, ó tipa bẹ́ẹ̀ dárí ẹ̀sẹ̀ wọn jì wọ́n, ó kà wọ́n sí olódodo, ó sì sọ wọ́n dọmọ. (Róòmù 3:23-26; 4:25; 8:30) Síbẹ̀, Róòmù orí 8 ṣe pàtàkì fáwọn tó nírètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ìdí ni pé lọ́nà kan, Ọlọ́run ka àwọn náà sí olódodo. Àwọn náà lè jàǹfàní láti inú ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà níbẹ̀ fún àwọn olódodo. w16.12 2:1-3

Tuesday, January 23

Ẹ má ṣàníyàn láé.​—Mát. 6:34.

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé”? Ó ṣe kedere pé kò ní in lọ́kàn pé gbogbo nǹkan á máa dùn yùngbà-yùngbà fáwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tàbí pé a ò ní róhun tó máa mú ká ṣàníyàn. Torí náà, ohun tí Jésù ń sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé kéèyàn máa ṣe àníyàn tí kò pọn dandan tàbí kéèyàn máa ṣàníyàn àṣejù kì í yanjú ìṣòro. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ló ní ìṣòro tiẹ̀, torí náà kò sídìí tí Kristẹni kan á fi máa pa àníyàn tàná àti tọ̀la mọ́ tòní. Tí Kristẹni kan bá ń ronú ṣáá nípa ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀, ó lè mú kó máa ṣàníyàn tí kò pọn dandan. Àmọ́, kò sídìí tó fi yẹ kó o máa kọ́kàn sókè lórí ohun tó lè má ṣẹlẹ̀. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan téèyàn ń rò kì í le tó béèyàn ṣe rò pó máa rí. Yàtọ̀ síyẹn, kò sí bí ìṣòro kan ṣe lè le tó táá kọjá agbára Ọlọ́run. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín, á sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn àníyàn tí wọ́n ní nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, èyí tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ àtèyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀. w16.12 3:13,16

Wednesday, January 24

Ọ̀gbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.​—Òwe 11:2.

Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Sọ́ọ̀lù nígbà tó jọba ní Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn sì mọyì rẹ̀ gan-an. (1 Sám. 9:1, 2, 21; 10:20-24) Àmọ́ kò pẹ́ lẹ́yìn tó di ọba ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó fi hàn pé kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ mọ́. Nígbà kan tí wòlíì Sámúẹ́lì kò tètè dé sí ìlú Gílígálì níbi tí wọ́n fàdéhùn sí, Sọ́ọ̀lù ṣe ohun tí kò yẹ kó ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ọmọ ogun Filísínì ń bọ̀ wá bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà pẹ̀lú Sọ́ọ̀lù sì sá fi í sílẹ̀. Sọ́ọ̀lù bá ronú pé, ‘Á dáa kí n tètè wá nǹkan ṣe, mi ò gbọ́dọ̀ jáfara.’ Ló bá ṣe ohun tí kò tọ́ sí i, ó rú ẹbọ sí Ọlọ́run, inú Jèhófà ò sì dùn sóhun tó ṣe. (1 Sám. 13:5-9) Nígbà tí Sámúẹ́lì dé Gílígálì, ó bá Sọ́ọ̀lù wí gidigidi. Dípò tí Sọ́ọ̀lù á fi gba ìbáwí, ṣe ló ń ṣàwáwí, ó ń di ẹ̀bi ru àwọn míì, kò sì ka ohun tó ṣe sí bàbàrà. (1 Sám. 13:10-14) Bí Sọ́ọ̀lù ṣe ń kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan ló ń bọ́ sórí òmíì títí Jèhófà fi kọ̀ ọ́ lọ́ba, tó sì pàdánù ojúure rẹ̀. (1 Sám. 15:22, 23) Ó mà ṣé o, ìbẹ̀rẹ̀ ayé Sọ́ọ̀lù dùn bí oyin, àmọ́ ìgbẹ̀yìn rẹ̀ wá korò bí iwọ.​—1 Sám. 31:1-6. w17.01 3:​1, 2

Thursday, January 25

Èmi ti rí Dáfídì . . . ọkùnrin kan tí ó tẹ́ ọkàn-àyà mi lọ́rùn. ​—Ìṣe 13:22.

Dáfídì jẹ́ olóòótọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà kan wà tó dẹ́ṣẹ̀ tó wúwo. Ó bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà. (2 Sám. 11:1-21) Dáfídì ò lè dáwọ́ aago pa dà sẹ́yìn. Bákan náà, kò sóhun tó lè ṣe tí kò fi ní jìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Kódà, á ṣì máa bá àwọn kan lára ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ yí jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀. (2 Sám. 12:10-12, 14) Torí náà, ó gba pé kí Dáfídì nígbàgbọ́. Ó ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé tóun bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Jèhófà máa dárí ji òun, á sì ran òun lọ́wọ́ láti fara da ìyà ẹ̀ṣẹ̀ òun. Torí pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe. Àwọn àṣìṣe kan wúwo ju àwọn míì lọ, ó sì lè má rọrùn fún wa láti yí ọwọ́ aago pa dà sẹ́yìn. Ó lè jẹ́ pé ṣe làá máa bá ìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà yí. (Gál. 6:7) Àmọ́, a gbà pé Jèhófà máa mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé tá a bá ronú pìwà dà, òun á dúró tì wá nígbà ìṣòro, kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àfọwọ́fà wa ni.​—Aísá. 1:18, 19; Ìṣe 3:19. w17.01 1:10-12

Friday, January 26

Aráyé kò . . . lè rídìí iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ oòrùn; bí ó ti wù kí aráyé máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ kárakára púpọ̀ tó láti wá a, síbẹ̀ wọn kò rídìí rẹ̀. Bí wọ́n sì tilẹ̀ sọ pé wọ́n gbọ́n tó láti mọ̀, wọn kò ní lè rídìí rẹ̀.​—Oníw. 8:17.

Tá a bá mọ̀wọ̀n ara wa, àá ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání kódà tá ò bá mọ ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Bí àpẹẹrẹ, bóyá a jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, a lè máa ronú pé, tí n bá ṣàìsàn ńkọ́? Táwọn òbí mi tó ti ń dàgbà bá nílò àbójútó ńkọ́? Tí èmi náà bá dàgbà, ta ló máa tọ́jú mi? Kò sí bá a ṣe ṣèwádìí tó tá a máa rí gbogbo ìdáhùn tá à ń fẹ́ sáwọn ìbéèrè yìí. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àá mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tá ò lè ṣe. Lẹ́yìn tá a bá ti ṣe àwọn ìwádìí tó yẹ, tá a bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà tá a sì gbàdúrà pé kí Jèhófà tọ́ wa sọ́nà, ohun tó kù ni pé ká ṣe ohun tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run bá darí wa pé ká ṣe. (Oníw. 11:4-6) Ìpinnu tá a bá ṣe ni Jèhófà máa wá bù kún tàbí kó darí wa pé ká ṣe nǹkan míì.​—Òwe 16:3, 9. w17.01 4:14

Saturday, January 27

Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀. ​—Jẹ́n. 2:17.

Ọwọ́ Ádámù àti Éfà lọ̀rọ̀ kù sí. Ṣé ọ̀rọ̀ Jèhófà ni wọ́n á tẹ̀ lé àbí ti ejò? Wọ́n yàn láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (Jẹ́n. 3:​6-13) Bí Ádámù àti Éfà ṣe dìtẹ̀ sí Jèhófà mú kí wọ́n di aláìpé. Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí wọ́n ṣe yẹn mú kí wọ́n di ọ̀tá Ọlọ́run torí pé Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi.” Torí náà, “kò lè gba ohun tí kò tọ́” láyè. (Háb. 1:13) Ká ní Ọlọ́run gbójú fo ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù, ó lè ṣèdíwọ́ fún àlááfíà àti ìṣọ̀kan tó wà láyé àti lọ́run. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, tí Ọlọ́run kò bá ṣe ohunkóhun nípa ọ̀tẹ̀ tó wáyé lọ́gbà Édẹ́nì, àwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì ì bá ronú pé bóyá lọ̀rọ̀ Jèhófà ṣeé gbára lé. Àmọ́ ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó fi lélẹ̀, kò sì ní yí i pa dà. (Sm. 119:142) Torí náà, ti pé Ádámù àti Éfà ní òmìnira kò ní kí wọ́n tàpá sí òfin Ọlọ́run. Torí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n kú, wọ́n sì pa dà di erùpẹ̀ tí Ọlọ́run fi dá wọn.​—Jẹ́n. 3:19. w17.02 1:8, 10, 11

Sunday, January 28

Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.​—Mát. 4:4.

Àtìgbà tí Jésù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ló ti ń jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ máa tọ́ òun sọ́nà. Kódà, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kó tó kú wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹ sí Mèsáyà lára. (Mát. 27:46; Lúùkù 23:46) Àmọ́ ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà yẹn máa ń da ọwọ́ bo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí kò bá ti bá àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn mu. Jésù sọ ohun tí wòlíì Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn èèyàn yẹn pé: “Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè [wọn] bọlá fún mi, síbẹ̀ ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi. Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni bí ẹ̀kọ́.” (Mát. 15:​7-9) Yàtọ̀ sí pé Jésù jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà nínú àwọn nǹkan tó ṣe, ó tún máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn. Nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń bá a fa ọ̀rọ̀, kò lo ọgbọ́n ara rẹ̀ tàbí ìrírí rẹ̀ láti fún wọn lésì, kàkà bẹ́ẹ̀ Ìwé Mímọ́ ló fi ń dá wọn lóhùn.​—Mát. 22:​33-40. w17.02 3:18, 19

Monday, January 29

Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo, . . . ẹ máa fi ọlá fún ọba.​—1 Pét. 2:17.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin ìjọba máa ń yàtọ̀ láti ibì kan sí òmíì, síbẹ̀ a máa ń tẹ̀ lé òfin tí wọ́n bá là sílẹ̀. Àmọ́ tí òfin tí wọ́n fún wa bá ta ko ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, a ò ní tẹ̀ lé e. A ò ní torí pé a fẹ́ bọ̀wọ̀ fún wọn ká wá tẹ òfin Ọlọ́run lójú tàbí ká ṣe ohun tó máa ba ẹ̀rí ọkàn wa jẹ́ tàbí ká lọ́wọ́ sóhun tí kò yẹ ká lọ́wọ́ sí. (1  Pét. 2:​13-16) Tó bá dọ̀rọ̀ bíbọ̀wọ̀ fáwọn aláṣẹ, a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ayé àtijọ́. Nígbà tí ìjọba Róòmù sọ pé káwọn èèyàn wá fi orúkọ sílẹ̀, Jósẹ́fù àti Màríà náà lọ forúkọ sílẹ̀. Wọ́n rìnrìn-àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù bó tilẹ̀ jẹ́ pé oyún Màríà ti ga gan-an, ó sì máa tó bímọ. (Lúùkù 2:​1-5) Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn èké kan Pọ́ọ̀lù, ó gbèjà ara rẹ̀ níwájú Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà àti Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó jẹ́ gómìnà Róòmù tó ń ṣàkóso Jùdíà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.​—Ìṣe 25:1-12; 26:1-3. w17.03 1:9, 10

Tuesday, January 30

Nǹkan wọ̀nyí . . . [ni a] kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún [wa]. ​—1 Kọ́r. 10:11.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í hùwàkiwà bíi tàwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì, Jèhófà ò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn mọ́. (Oníd. 2:1-3, 11-15; Sm. 106:40-43) Kò sí àní-àní pé nígbà yẹn, á nira gan-an fáwọn ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà láti máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé àwọn olóòótọ́ kan ṣì wà bíi Jẹ́fútà, Ẹlikénà, Hánà àti Sámúẹ́lì. Wọ́n pinnu pé ohun tínú Jèhófà dùn sí làwọn á máa ṣe. (1 Sám. 1:20-28; 2:26) Lóde òní, ṣe làwọn èèyàn ń ronú tí wọ́n sì ń hùwà bíi tàwọn ọmọ ilẹ̀ Kénáánì. Ṣe ni wọ́n ń hùwà ipá lọ ràì, tí wọ́n ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn wá owó kiri, ìṣekúṣe ò sì jẹ́ nǹkan kan lójú wọn. Àmọ́, Jèhófà ti fún wa ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere. Bó ṣe ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó fẹ́ dáàbò bò wá káwọn èèyàn ayé yìí má bàa kéèràn ràn wá. Ǹjẹ́ kò yẹ ká kọ́gbọ́n látinú àṣìṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (1 Kọ́r. 10:6-10) A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe ká má bàa lọ bẹ̀rẹ̀ sí í ronú báwọn èèyàn ayé ṣe ń ronú. (Róòmù 12:2) Ṣé a máa sa gbogbo ipá wa láti ṣe bẹ́ẹ̀? w16.04 1:4-6

Wednesday, January 31

Ẹni òye . . . ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.​—Òwe 1:5.

Tó bá di pé ká ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, kò yẹ ká kánjú, ṣe ló yẹ ká ronú dáadáa, ká sì gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa rẹ̀. Ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa fún wa ní gbogbo ohun tá a nílò láti ṣèpinnú tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Torí náà, nígbàkigbà tó o bá fẹ́ ṣèpinnu pàtàkì, máa bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ ìpinnu mi yìí fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà? Ṣé á múnú àwọn ará ilé mi dùn, táá sì jẹ́ ká wà ní àlàáfíà? Ṣé á fi hàn pé mo ní sùúrù, mo sì jẹ́ onínúure?’ Jèhófà kì í fipá mú wa pé ká nífẹ̀ẹ́ òun tàbí ká jọ́sìn òun. Torí pé Ọlọ́run fún wa lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá, ó gbà pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu bóyá a máa sin òun tàbí a ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. (Jóṣ. 24:15; Oníw. 5:4) Àmọ́, ó retí pé ká ṣe àwọn ìpinnu tó bá ìmọ̀ràn òun mu. Torí náà, tá a bá gbà pé àwọn ìtọ́ni Jèhófà ló dára jù, tá a sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, àá máa ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, ọ̀nà wa sì máa yọrí sí rere.​—Ják. 1:5-8; 4:8. w17.03 2:17, 18

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́