ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • es19 ojú ìwé 88-97
  • September

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • September
  • Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Sunday, September 1
  • Monday, September 2
  • Tuesday, September 3
  • Wednesday, September 4
  • Thursday, September 5
  • Friday, September 6
  • Saturday, September 7
  • Sunday, September 8
  • Monday, September 9
  • Tuesday, September 10
  • Wednesday, September 11
  • Thursday, September 12
  • Friday, September 13
  • Saturday, September 14
  • Sunday, September 15
  • Monday, September 16
  • Tuesday, September 17
  • Wednesday, September 18
  • Thursday, September 19
  • Friday, September 20
  • Saturday, September 21
  • Sunday, September 22
  • Monday, September 23
  • Tuesday, September 24
  • Wednesday, September 25
  • Thursday, September 26
  • Friday, September 27
  • Saturday, September 28
  • Sunday, September 29
  • Monday, September 30
Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2019
es19 ojú ìwé 88-97

September

Sunday, September 1

[Ẹ máa tọ́ àwọn ọmọ yín] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.​—Éfé. 6:4.

Ọ̀kan lára àwọn ojúṣe pàtàkì táwọn òbí ní ni pé kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Sm. 127:3) Nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gbàrà tí wọ́n bá ti bímọ ni ọmọ náà ti jẹ́ ti Jèhófà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa Kristẹni ò rí bẹ́ẹ̀. Ti pé àwọn òbí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́ kò túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ náà máa ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, gbàrà táwọn òbí bá ti bímọ ni kí wọ́n ti fi sọ́kàn pé àwọn fẹ́ kọ́mọ náà ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó sì ṣèrìbọmi. Àbí kí ló tún ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ? Ó ṣe tán, kí ẹnì kan tó lè la ayé burúkú yìí já, ó gbọ́dọ̀ ya ara rẹ̀ sí mímọ́, kó ṣèrìbọmi, kó sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. (Mát. 24:13) Àdúrà wa ni pé kí ẹ̀yin òbí náà ní irú ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn téèyàn máa ń ní táwọn ọmọ rẹ̀ bá ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì ń fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó. w18.03 12 ¶16-17

Monday, September 2

Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ.​—1 Tím. 4:16.

Tí àwọn alàgbà àtàwọn òbí bá fẹ́ báni wí, á dáa kí wọ́n fara wé Jésù. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á fi hàn pé wọ́n fẹ́ kí Jèhófà àti Jésù máa darí àwọn. Ká sòótọ́, a ò lè kaye ìbùkún tá a máa rí tá a bá ń gba ìbáwí Jèhófà, tá a sì ń fara wé Jèhófà àti Jésù táwa náà bá ń báni wí. Lára ẹ̀ ni pé, ìdílé wa máa tòrò, àlàáfíà sì máa wà nínú ìjọ. Ọkàn gbogbo wa máa balẹ̀, ara á tù wá, àá sì nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú. Ìtọ́wò lásán lèyí tá a bá fi wé àwọn nǹkan tá a máa gbádùn nínú ayé tuntun. (Sm. 72:7) Kò sí àní-àní pé ìbáwí Jèhófà ń kọ́ wa bá a ṣe lè máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà títí láé, ká sì wà níṣọ̀kan bí ìdílé kan lábẹ́ àbójútó Baba wa ọ̀run. (Aísá. 11:9) Tá a bá ń fojú tó tọ́ wo ìbáwí Jèhófà, ìyẹn á jẹ́ ká mọyì ìbáwí rẹ̀, ká sì gbà pé lóòótọ́ ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. w18.03 26 ¶15; 27 ¶17, 19

Tuesday, September 3

Ó sì batisí àwọn ènìyàn ní Odò Jọ́dánì, tí wọ́n ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba.​—Mát. 3:6.

Ìrìbọmi àkọ́kọ́ tí Bíbélì mẹ́nu kàn lèyí tí Jòhánù Oníbatisí ṣe fáwọn èèyàn. (Mát. 3:​1-6) Ìdí táwọn èèyàn sì fi wá ṣèrìbọmi ni pé wọ́n fẹ́ fi hàn pé àwọn ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ táwọn dá lòdì sí Òfin Mósè. Àmọ́, ìrìbọmi kan wà tí Jòhánù ṣe tó gba àfíyèsí tó sì ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ìrìbọmi tó ṣe fún Jésù, Ọmọ Ọlọ́run. (Mát. 3:​13-17) Ẹni pípé ni Jésù, kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, kò sì nílò ìrònúpìwàdà. (1 Pét. 2:22) Torí náà, ṣe ni ìrìbọmi rẹ̀ fi hàn pé ó ti ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Héb. 10:⁠7) Lásìkò tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà ṣèrìbọmi fáwọn èèyàn. (Jòh. 3:22; 4:​1, 2) Bíi ti ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe, ìrìbọmi táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe fáwọn èèyàn jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn èèyàn náà ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá lòdì sí Òfin Mósè. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù kú tó sì jíǹde, ìdí táwọn tó fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù fi máa ṣèrìbọmi á yàtọ̀ síyẹn. w18.03 5 ¶6-7

Wednesday, September 4

Ènìyàn ti ẹ̀mí ní tòótọ́ a máa wádìí ohun gbogbo wò.​—1 Kọ́r. 2:15.

Kí ló túmọ̀ sí pé ẹnì kan jẹ́ “ènìyàn ti ẹ̀mí”? Ẹni tẹ̀mí yàtọ̀ pátápátá sí ẹni tara ní ti pé èrò Ọlọ́run lẹni tẹ̀mí máa ń ní. Ẹni tẹ̀mí máa ń sapá kó lè “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfé. 5:1) Lédè míì, ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti mú èrò rẹ̀ bá ti Ọlọ́run mu, ó sì máa ń fi ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó. Ó máa ń ro ti Ọlọ́run mọ́ gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Àwọn nǹkan tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu làwọn ẹni tẹ̀mí máa ń ṣe, wọn ò dà bí àwọn ẹni tara tí kò mọ̀ ju nǹkan tara lọ. (Sm. 119:33; 143:10) Ẹni tẹ̀mí kì í lọ́wọ́ nínú àwọn nǹkan tí Bíbélì pè ní iṣẹ́ ti ara, kàkà bẹ́ẹ̀ “èso ti ẹ̀mí” ló fi ń ṣèwà hù. (Gál. 5:​22, 23) Ẹ jẹ́ ká ṣàkàwé ẹni tẹ̀mí báyìí: Tẹ́nì kan bá já fáfá nídìí iṣẹ́ rẹ̀ tí kì í sì í fi iṣẹ́ ṣeré, a máa ń pe onítọ̀hún ní akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. Lọ́nà kan náà, tẹ́nì kan bá ń fọwọ́ gidi mú àwọn nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, a máa ń pè é ní ẹni tẹ̀mí. w18.02 19 ¶3, 6

Thursday, September 5

Dáníẹ́lì, ìwọ ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.​—Dán. 10:11.

Ẹrú ni Dáníẹ́lì nílùú Bábílónì, àwọn abọ̀rìṣà àtàwọn abẹ́mìílò ló sì kún ibẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn Bábílónì máa ń fojú burúkú wo àwọn Júù, wọ́n máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì máa ń tẹ́ńbẹ́lú Jèhófà Ọlọ́run wọn. (Sm. 137:​1, 3) Ẹ wo bíyẹn ṣe máa ká Dáníẹ́lì àtàwọn Júù olóòótọ́ bíi tiẹ̀ lára! Ìgbà kan tiẹ̀ wà tọ́rọ̀ oúnjẹ di wàhálà torí Dáníẹ́lì ti pinnu pé òun ò ní “sọ ara òun di eléèérí nípasẹ̀ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba.” (Dán. 1:​5-8, 14-17) Ohun míì wà tó lè dán ìgbàgbọ́ Dáníẹ́lì wò. Dáníẹ́lì ní ọgbọ́n àti òye tó ṣàrà ọ̀tọ̀, èyí sì jẹ́ kó ní àwọn ojúṣe pàtàkì kó sì dẹni ńlá ní Bábílónì. (Dán. 1:​19, 20) Àmọ́ dípò kó máa gbéra ga tàbí kó máa pàṣẹ wàá, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, Jèhófà ló sì ń gbé gbogbo ògo fún. (Dán. 2:30) Kódà, ìgbà tí Dáníẹ́lì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ ni Jèhófà ti kà á mọ́ Nóà àti Jóòbù tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́. (Ìsík. 14:14) Ṣó tọ̀nà bí Ọlọ́run ṣe ka Dáníẹ́lì sí olódodo? Bẹ́ẹ̀ ni, ó tọ̀nà! Ìdí sì ni pé Dáníẹ́lì jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn títí tó fi kú. w18.02 5 ¶11-12

Friday, September 6

Léfì se àsè ìṣenilálejò rẹpẹtẹ fún [Jésù] ní ilé rẹ̀.​—Lúùkù 5:29.

Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ tó bá di pé ká gbádùn ara ẹni láìṣe àṣejù. Bí àpẹẹrẹ, ó lọ sí “àsè ìgbéyàwó kan,” ó sì tún lọ sí “àsè ìṣenilálejò” ńlá kan. (Jòh. 2:​1-10) Nígbà tó wà níbi ìgbéyàwó náà, ó sọ omi di ọtí wáìnì, èyí ló sì mú káwọn èèyàn rí wáìnì mu lẹ́yìn tí èyí tó wà tẹ́lẹ̀ ti tán. Bó ti wù kó rí, kì í ṣe adùn tàbí fàájì ni Jésù fi gbogbo ayé rẹ̀ lé. Ìfẹ́ Jèhófà ló gbawájú láyé rẹ̀, ó sì lo gbogbo okun rẹ̀ torí àwọn míì. Kódà, ó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀, ó sì kú ikú oró káwọn míì lè wà láàyè. Nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mát. 5:​11, 12) Tó bá jẹ́ lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kì í ṣe àwọn nǹkan tó máa bí Jèhófà nínú nìkan la máa yẹra fún, kódà a ò tún ní lọ́wọ́ sáwọn nǹkan tá a fura sí pé inú rẹ̀ lè má dùn sí.​—Mát. 22:​37, 38. w18.01 26 ¶16-18

Saturday, September 7

Bí ènìyàn bá ń kẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkẹ́jù láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, ní ìkẹyìn ìgbésí ayé rẹ̀, yóò di aláìmọ ọpẹ́ dá pàápàá.​—Òwe 29:21.

Ìdí tá a fi ń fún Jèhófà ní nǹkan ni pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a sì mọyì rẹ̀ gan-an. Orí wa máa ń wú tá a bá ń ronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe torí tiwa. Ọba Dáfídì sọ pé Jèhófà ló fún wa ní gbogbo ohun tá a ní, torí náà kò sóhun tá a lè fún Jèhófà tí kì í ṣe pé òun ló kọ́kọ́ fún wa. (1 Kíró. 29:​11-14) Ọrẹ ṣíṣe máa ń ṣe wá láǹfààní. Ó yẹ kó máa wù wá láti fúnni dípò ká máa wá bá a ṣe máa gba tọwọ́ àwọn èèyàn. Ẹ jẹ́ ká ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ báyìí: Ká sọ pé òbí kan máa ń fún ọmọ rẹ̀ lówó ìpápánu, àmọ́ tọ́mọ náà wá ń tọ́jú díẹ̀díẹ̀ pa mọ́ nínú rẹ̀ tó sì wá fi ra ẹ̀bùn fáwọn òbí rẹ̀. Báwo ló ṣe máa rí lára àwọn òbí náà? Bákan náà, ọmọ kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àmọ́ tó ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ lè fún àwọn òbí rẹ̀ lówó díẹ̀ kí wọ́n lè fi kún owó tí wọ́n fi ń bójú tó ilé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí yìí lè má retí pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n máa gbà á tìfẹ́tìfẹ́ torí ìyẹn máa jẹ́ kí ọmọ náà fi hàn pé òun mọyì gbogbo nǹkan tí wọ́n ti ṣe fún òun. Jèhófà náà mọ̀ pé tá a bá ń ṣe ọrẹ látinú àwọn nǹkan ìní wa, ó máa ṣe wá láǹfààní. w18.01 18 ¶4, 6

Sunday, September 8

Kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ.​—Diu. 30:19.

Tó o bá fẹ́ káwọn ọmọ rẹ nígbàgbọ́, ó kọjá kó o kàn máa sọ fún wọn pé ohun kan ló tọ́ tàbí pé ohun kan ni kò tọ́. Á dáa kó o tún mọ èrò wọn. O ò ṣe bi wọ́n láwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé kó o sá fún àwọn nǹkan tí ẹran ara ń fẹ́? Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ìgbà gbogbo làwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣeni láǹfààní?’ (Aísá. 48:​17, 18) Ohun míì wà tó tún yẹ kó o jíròrò pẹ̀lú ọmọ rẹ tó fẹ́ ṣèrìbọmi. Ṣó mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn ṣèrìbọmi àti ojúṣe tó wé mọ́ jíjẹ́ Kristẹni? Àǹfààní wo ló máa rí tó bá ṣèrìbọmi? Àwọn ìṣòro wo ló lè jẹ yọ? Báwo làwọn àǹfààní ibẹ̀ ṣe ju àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó yọjú lọ? (Máàkù 10:​29, 30) Ó ṣeé ṣe kó dojú kọ àwọn ipò tó máa dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kọ́mọ rẹ ronú jinlẹ̀ nípa àwọn ìbéèrè yìí dáadáa kó tó ṣèrìbọmi. Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ rọrùn fún wọn láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, wọ́n á sì ní ìdánilójú pé ìgbà gbogbo làwọn ìlànà Bíbélì máa ń ṣeni láǹfààní. w17.12 21-22 ¶14-15

Monday, September 9

Àní orúkọ ni ó fi ń pe gbogbo wọn.​—Aísá. 40:26.

Ọ̀pọ̀ lára ẹ̀yin ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń fara da àìsàn tó le. Ara ti ń dara àgbà fáwọn kan, síbẹ̀ wọ́n tún láwọn arúgbó tí wọ́n ń tọ́jú. Ṣe làwọn kan ń tiraka kí wọ́n lè rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu, bí wọ́n ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé wọn ni wọ́n ń wá, kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa ní ànító àti àníṣẹ́kù. Bá a ṣe mọ̀, ńṣe làwọn ìṣòro yìí ń rọ́ lura fáwọn kan lára wa, ó mà ṣe o! Tí Jèhófà bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí, mélòómélòó wá ni ìwọ tó ò ń fi tọkàntọkàn sìn ín torí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Sm. 19:​1, 3, 14) Baba wa ọ̀run mọ̀ ẹ́ dáadáa. Kódà, ‘gbogbo irun orí rẹ ni Jèhófà ti kà.’ (Mát. 10:30) Onísáàmù náà tún jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ohun táwọn aláìní-àléébù ń kojú. (Sm. 37:18) Ó mọ gbogbo ìṣòro tó ò ń dojú kọ, ó sì máa fún ẹ lókun láti fara dà á. w18.01 7 ¶1; 8 ¶4

Tuesday, September 10

Tàbítà, dìde!​—Ìṣe 9:40.

Àpọ́sítélì Pétérù jí Tàbítà dìde, ó sì ya àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́nu gan-an débi pé ‘ọ̀pọ̀ ènìyàn di onígbàgbọ́ nínú Olúwa.’ Ó dájú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí á jẹ́rìí nípa Jésù, wọ́n á sì sọ fáwọn míì pé Jèhófà lè jí òkú dìde. (Ìṣe 9:​36-42) Àjíǹde míì tún wáyé níṣojú àwọn èèyàn. Ìgbà kan wà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ará nínú yàrá òkè kan nílùú Tíróásì, tó jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí. Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ̀rọ̀ títí di òru. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Yútíkọ́sì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ wíńdò, ó ń gbọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ. Àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í tòògbé, ló bá ré bọ́ látorí àjà kẹta ilé náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Lúùkù oníṣègùn ló kọ́kọ́ dé ọ̀dọ̀ Yútíkọ́sì kó lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Lẹ́yìn tí Lúùkù sì ti yẹ̀ ẹ́ wò, ó rí i pé kì í ṣe pé Yútíkọ́sì ṣèṣe tàbí pé ó dákú, ṣe ló kú fin-ín-fin-ín, ìyẹn sì ba àwọn ará nínú jẹ́ gan-an. Pọ́ọ̀lù sọ̀ kalẹ̀, ó gbé òkú náà mọ́ra, ó wá sọ pé: Ó ti jíǹde o! Ẹ ò rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn máa wú àwọn tó wà níbẹ̀ lórí gan-an! Bí wọ́n ṣe mọ̀ pé ọmọkùnrin náà ti kú tẹ́lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù sì jí i dìde mú kí wọ́n ní ìtùnú “lọ́nà tí kò ṣeé díwọ̀n.”​—Ìṣe 20:​7-12. w17.12 5 ¶10-11

Wednesday, September 11

Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà.​—Sm. 46:8.

Ṣé òótọ́ ni pé aráyé ti rí ojútùú sí àwọn ìṣòro tó ti ń bá aráyé fínra tipẹ́? Àwọn èèyàn ṣì ń bára wọn jagun. Síbẹ̀ àwọn ìwà burúkú míì ti gbòde kan, àwọn ìwà bíi kí wọ́n máa fi íńtánẹ́ẹ̀tì lu jìbìtì, káwọn tọkọtaya máa lu ara wọn bí ẹni máa kú, káwọn afẹ̀míṣòfò sì máa pààyàn nípakúpa túbọ̀ ń peléke sí i níbi gbogbo láyé. Àwọn èèyàn tí kò mọ̀ ju tara wọn nìkan ló wà nídìí òṣèlú àti ọrọ̀ ajé. Torí náà, wọn ò lè fòpin sí ogun, ìwà ọ̀daràn, àìsàn àti ipò òṣì. Ó dájú pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè palẹ̀ wọn mọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Jèhófà máa ṣe fún aráyé. Ogun: Ìjọba Ọlọ́run máa mú gbogbo ohun tó ń fa ogun kúrò, títí kan ìmọtara-ẹni-nìkan, ìwà jẹgúdújẹrá, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, ẹ̀sìn èké àti Sátánì alára. (Sm. 46:9) Ìwà Ọ̀daràn: Àwọn tó fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run ti kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa gbé ní àlàáfíà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì finú tán ara wọn. Kò sí ìjọba èèyàn tó lè ṣerú ẹ̀. (Aísá. 11:9) Àìsàn: Jèhófà máa mú káwọn èèyàn ní ìlera pípé, àìsàn á sì pòórá. (Aísá. 35:​5, 6) Ipò Òṣì: Jèhófà máa rí i dájú pé ipò òṣì di ohun ìgbàgbé, á sì pèsè ohun tí aráyé nílò lọ́pọ̀ yanturu nípa tara àti nípa tẹ̀mí.​—Sm. 72:​12, 13. w17.11 24 ¶14-16

Thursday, September 12

Kí ó má sì sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kankan lórí rẹ.​—Diu. 19:10.

Ìdí pàtàkì tí Jèhófà fi ṣètò àwọn ìlú ààbò ni pé kò fẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Jèhófà ka ẹ̀mí sí pàtàkì, ó sì kórìíra “ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 6:​16, 17) Torí pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ àti onídàájọ́ òdodo, kì í gbójú fo ìpànìyàn, kódà kó jẹ́ èyí tó ṣèèṣì ṣẹlẹ̀. Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ò fìwà jọ Jèhófà torí pé ẹ̀mí èèyàn ò jọ wọ́n lójú. Lọ́nà wo? Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú kọ́kọ́rọ́ ìmọ̀ lọ; ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, àwọn tí wọ́n sì ń wọlé ni ẹ dí lọ́wọ́!” (Lúùkù 11:52) Àwọn ló yẹ kó máa ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, ṣe ni wọ́n ń mú káwọn èèyàn náà kẹ̀yìn sí Jésù tó jẹ́ “Olórí Aṣojú ìyè,” wọ́n sì mú kí wọ́n máa tọ ọ̀nà ìparun. (Ìṣe 3:15) Agbéraga àti onímọtara-ẹni-nìkan làwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí, wọn ò sì bìkítà fáwọn Júù bíi tiwọn. Ẹ ò rí i pé ìkà àti aláìláàánú ni wọ́n! w17.11 15 ¶9-10

Friday, September 13

Ẹnì yòówù tí ó bá tijú mi . . . , Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò tijú rẹ̀.​—Máàkù 8:38.

Ó lè jẹ́ pé a ò sọ fún àwọn ìdílé wa nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ tí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lágbára, a bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún wọn. Kí lo lè ṣe táwọn mọ̀lẹ́bí rẹ bá ta kò ẹ́ torí pé o yàn láti sin Jèhófà? Á dáa kó o mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú wa dùn pé a kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, àwọn mọ̀lẹ́bí wa lè ronú pé ńṣe làwọn ajẹ́rìí ń tàn wá jẹ tàbí pé wọ́n ti mú wa wọnú ẹgbẹ́ wọn. Wọ́n lè ronú pé a ò nífẹ̀ẹ́ àwọn mọ́ torí pé a ò bá wọn ṣọdún mọ́. Wọ́n tiẹ̀ lè máa bẹ̀rù pé ẹ̀sìn tá a gbà máa mú wa ṣìnà. Torí náà, ó ṣe pàtàkì ká fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó ń bà wọ́n lẹ́rù, ìyẹn á jẹ́ ká lóye wọn ká sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. (Òwe 20:5) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sapá láti lóye “ènìyàn gbogbo” kó bàa lè wàásù ìhìn rere fún wọn, ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn.​—1 Kọ́r. 9:​19-23. w17.10 15 ¶11-12

Saturday, September 14

Ẹ kọ orin atunilára sí [Jèhófà].​—Sm. 33:2.

Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa bà wá láti kọrin torí pé kò dá wa lójú pé a mọ béèyàn ṣe ń kọrin. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tá a lè ṣe táá jẹ́ ká túbọ̀ mọ orin kọ. Tó o bá fẹ́ morin kọ dáadáa kí ohùn rẹ sì já geere, ó yẹ kó o mọ béèyàn ṣe ń mí sínú mí síta bó ṣe yẹ. Bí iná mànàmáná ṣe máa ń mú kí gílóòbù tàn yòò, bẹ́ẹ̀ náà ni mímí ṣe máa ń jẹ́ ká lè kọrin tàbí sọ̀rọ̀ sókè. Bí ohùn wa ṣe máa ń ròkè tá a bá ń sọ̀rọ̀ náà ló ṣe yẹ kí ohùn wa ròkè tá a bá ń kọrin, ó tiẹ̀ yẹ kó ròkè ju bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Tó bá dọ̀rọ̀ orin kíkọ, Ìwé Mímọ́ gba àwa èèyàn Jèhófà níyànjú pé ká “fi ìdùnnú ké jáde.” (Sm. 33:​1-3) Gbìyànjú àbá yìí wò: Yan ọ̀kan lára àwọn orin tó o fẹ́ràn jù nínú ìwé orin wa. Ka ọ̀rọ̀ orin náà jáde sókè, má ṣe jẹ́ kí ohùn rẹ gbọ̀n, kó o sì jẹ́ kó rinlẹ̀. Lẹ́yìn náà, lo ohùn kan náà yẹn láti ka ìlà kan lára orin náà láìdá ẹnu dúró. Wá fi ohùn tó ròkè yẹn kọ ìlà náà. (Aísá. 24:14) Kó o tó mọ̀, ohùn rẹ á máa jáde sókè bó o bá ń kọrin. Kò jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ náà ti ń morin kọ nìyẹn. Torí náà, má ṣe jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́ tàbí kí ojú tì ẹ́! w17.11 5-6 ¶11-13

Sunday, September 15

Olúkúlùkù ẹni tí Ọlọ́run tòótọ́ ta ẹ̀mí rẹ̀ jí, láti gòkè lọ tún ilé Jèhófà kọ́, èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.​—Ẹ́sírà 1:5.

Kí ló ṣeé ṣe káwọn Júù yẹn máa rò bí wọ́n ṣe ń rìnrìn-àjò náà? Ó dájú pé wọ́n á máa ronú nípa bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa rí. Wọ́n ti gbọ́ nípa bí ìlú náà ṣe rẹwà tó nígbà kan. Ó sì ṣeé ṣe káwọn tó dàgbà láàárín wọn máa sọ bí tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe lẹ́wà tó. (Ẹ́sírà 3:12) Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà bá wọn rìnrìn-àjò yẹn, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ nígbà tó o bá kọ́kọ́ rí àwókù ìlú Jerúsálẹ́mù, tó o sì mọ̀ pé ibẹ̀ ni wàá máa gbé báyìí? Ṣé àyà rẹ ò ní já tó o bá rí àwọn ilé tó ti di àlàpà, tí igbó ti bò mọ́lẹ̀? Tó o bá ń rántí àwọn ògiri gìrìwò tó nípọn tó yí Bábílónì ká, ṣé ọkàn rẹ ò ní bà jẹ́ bó o ṣe ń wo àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù tó ti ya lulẹ̀? Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà ò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wọn. Wọ́n ti rí bí Jèhófà ṣe dáàbò bò wọ́n nígbà ìrìn-àjò wọn pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Gbàrà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, ohun àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n mọ pẹpẹ kan síbi tí tẹ́ńpìlì wà tẹ́lẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í rúbọ sí Jèhófà lójoojúmọ́.​—Ẹ́sírà 3:​1, 2. w17.10 26-27 ¶2-3

Monday, September 16

Má fòyà tàbí kí o jáyà, nítorí Jèhófà . . . wà pẹ̀lú rẹ.​—1 Kíró. 28:20.

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìrírí bàbá rẹ̀ ni Sólómọ́nì ti kọ́ bó ṣe lè nígboyà. Ìgboyà tí Dáfídì ní ló mú kó lè kojú Gòláyátì tó jẹ́ òmìrán. Jèhófà ran Dáfídì lọ́wọ́ tó fi jẹ́ pé òkúta kan péré ló fi mú ọkùnrin náà balẹ̀. (1 Sám. 17:​45, 49, 50) Abájọ tí Dáfídì fi rọ Sólómọ́nì pé kó jẹ́ onígboyà, kó sì kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Jèhófà máa wà pẹ̀lú rẹ̀ títí tó fi máa kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí. Ó ṣe kedere pé Sólómọ́nì fi àwọn ọ̀rọ̀ yẹn sọ́kàn. Láìka pé ọ̀dọ́ ni tí kò sì nírìírí, ó lo ìgboyà, ó gbé iṣẹ́ ṣe, Jèhófà sì ràn án lọ́wọ́ tó fi parí iṣẹ́ náà ní ọdún méje àtààbọ̀. Bí Jèhófà ṣe ran Sólómọ́nì lọ́wọ́, ó máa ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ tó gbé fún wa yanjú, nínú ìdílé àti nínú ìjọ. (Aísá. 41:​10, 13) Tá a bá ń lo ìgboyà nínú ìjọsìn Jèhófà, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. w17.09 28 ¶3; 29 ¶4; 32 ¶20-21

Tuesday, September 17

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.​—Héb. 4:12.

Àwa èèyàn Jèhófà mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “yè, ó sì ń sa agbára.” Ọ̀pọ̀ wa ló ti rí i pé Bíbélì lágbára láti tún ìgbésí ayé èèyàn ṣe. Àwọn Kristẹni kan ti fìgbà kan rí jẹ́ olè, ajoògùnyó tàbí oníṣekúṣe. Àwọn kan tiẹ̀ ti rọ́wọ́ mú gan-an nínú ayé, àmọ́ wọn ò láyọ̀. (Oníw. 2:​3-11) Ìgbésí ayé àwọn míì ò nítumọ̀ tẹ́lẹ̀, wọn ò sì nírètí. Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n ń láyọ̀, ìgbésí ayé wọn sì nítumọ̀. A sábà máa ń ka ìrírí àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nínú Ilé Ìṣọ́, lábẹ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Bíbélì Máa Ń Yí gbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà,” a sì máa ń gbádùn àwọn ìrírí náà. Bó ti wù kó rí, lẹ́yìn téèyàn bá ṣèrìbọmi, ó ṣì gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run lè túbọ̀ lágbára. w17.09 23 ¶1

Wednesday, September 18

Nínú ìyọ́nú Jèhófà lórí rẹ̀, . . . wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti mú un jáde àti láti mú un dúró ní òde ìlú ńlá náà.​—Jẹ́n. 19:16.

Àpẹẹrẹ Lọ́ọ̀tì fi hàn pé Jèhófà ń kíyè sí ìṣòro tó ń dé bá àwọn tó ń fòótọ́ ọkàn sìn ín, ó sì mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn. (Aísá. 63:​7-9; Ják. 5:11; 2 Pét. 2:9) Yàtọ̀ sí pé Jèhófà máa ń fàánú hàn, ó tún ń kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ báwọn náà ṣe lè máa fàánú hàn. Àpẹẹrẹ kan ni òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ohun ìdógò tẹ́nì kan lè gbà. (Ẹ́kís. 22:​26, 27) Ẹnì kan tí kò lójú àánú lè sọ pé òun á gba aṣọ ìbora ẹni tó yá lówó, tí onítọ̀hún kò sì ní rí aṣọ bora mọ́jú nínú otútù. Àmọ́, Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀. Ṣe ló yẹ kí wọ́n máa fàánú hàn síra wọn. Kí la rí kọ́ nínú ìlànà tó wà nínú òfin yẹn? Ohun tá a kọ́ ni pé táwọn ará wa bá wà nínú ìṣòro, ṣe ni ká ràn wọ́n lọ́wọ́ dípò tá a fi máa dágunlá.​—Kól. 3:12; Ják. 2:​15, 16; 1 Jòh. 3:17. w17.09 9 ¶4-5

Thursday, September 19

Baba, dárí jì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.​—Lúùkù 23:34.

Jésù gbàdúrà pé kí Bàbá rẹ̀ dárí ji àwọn tó fẹ́ pa á. Àbí ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà ni Jésù fi lélẹ̀ tó bá di pé ká níwà tútù, ká sì ní sùúrù kódà láwọn ipò tí kò rọgbọ. (1 Pét. 2:​21-23) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ oníwà tútù, a sì ní sùúrù? Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kól. 3:13) Tá a bá ń dárí jini, ìṣọ̀kan á túbọ̀ máa gbilẹ̀ nínú ìjọ. Àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ níwà tútù, ká sì ní sùúrù. Ìdí ni pé àwọn ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì tá a bá máa rí ìyè àìnípẹ̀kun. (Mát. 5:5; Ják. 1:21) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, àwọn ànímọ́ yìí máa ń jẹ́ ká lè bọlá fún Jèhófà, ká sì ran àwọn míì lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.​—Gál. 6:1; 2 Tím. 2:​24, 25. w17.08 25-26 ¶15-17

Friday, September 20

Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.​—2 Pét. 2:9.

Nínú Bíbélì, ọ̀pọ̀ ìgbà la rí bí Jèhófà ṣe gba ọ̀nà àrà dáhùn àdúrà àwọn èèyàn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Hesekáyà ló ń jọba nígbà tí Senakéríbù ọba Ásíríà gbógun ja ilẹ̀ Júdà, ó sì ṣẹ́gun gbogbo àwọn ìlú tó yí Jerúsálẹ́mù ká. (2 Ọba 18:​1-3, 13) Lẹ́yìn náà, Senakéríbù gbógun ti ìlú Jerúsálẹ́mù. Kí ni Ọba Hesekáyà ṣe nígbà tó mọ̀ pé àwọn ọ̀tá yìí ń kógun bọ̀? Ṣe ló gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ wòlíì Aísáyà. (2 Ọba 19:​5, 15-20) Síbẹ̀, Hesekáyà ò jókòó tẹtẹrẹ, ó san ìṣákọ́lẹ̀ tí Senakéríbù bù lé e, kó lè pẹ̀tù sọ́kàn rẹ̀. (2 Ọba 18:​14, 15) Nígbà tó yá, Hesekáyà bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún ogun. (2 Kíró. 32:​2-4) Àmọ́ báwo ni Jèhófà ṣe yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀ yìí? Jèhófà rán áńgẹ́lì kan láti pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Senakéríbù ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo. Ká sòótọ́, Hesekáyà gan-an ò lè ronú ẹ̀ láé pé ohun tí Jèhófà máa ṣe nìyẹn!​—2 Ọba 19:35. w17.08 10 ¶7; 11 ¶12

Saturday, September 21

Ẹ máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo di ọmọ ẹ̀yìn . . . , ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.​—Mát. 28:​19, 20.

Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe báyìí táá jẹ́ kọ́wọ́ rẹ tẹ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, á dáa kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ torí pé ìyẹn láá jẹ́ kó o lè fayé rẹ sin Jèhófà. Torí náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, máa ronú lórí ohun tó ò ń kọ́, kó o sì máa ṣe ohun táá gbé àwọn míì ró nípàdé. Tó bá jẹ́ pé o ṣì wà níléèwé, lo àǹfààní yẹn láti kọ́ ara rẹ kó o lè túbọ̀ jáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, máa fọgbọ́n bi wọ́n ní ìbéèrè kó o lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, kó o sì rí i pé o tẹ́tí sí ìdáhùn wọn. Bákan náà, máa yọ̀ǹda ara rẹ tí ìjọ bá níṣẹ́. O lè yọ̀ǹda láti máa bójú tó Gbọ̀ngàn Ìjọba. Rántí pé àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn ni Jèhófà máa ń lò. (Sm. 110:3; Ìṣe 6:​1-3) Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì dara pọ̀ mọ́ òun nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì torí pé àwọn arákùnrin “ròyìn rẹ̀ dáadáa.”​—Ìṣe 16:​1-5. w17.07 23 ¶7; 26 ¶14

Sunday, September 22

Gbogbo eékún yóò tẹ̀ ba fún mi, gbogbo ahọ́n yóò búra.​—Aísá. 45:23.

Kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó lè wà, àfi kí ọ̀rọ̀ ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso yanjú, kó sì ṣe kedere sáwọn èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, rúgúdù á ṣì máa ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn èèyàn níbi gbogbo àti nínú ìdílé. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jèhófà bá ti yanjú ọ̀rọ̀ náà, gbogbo ẹ̀dá láá fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀ títí láé. Nípa bẹ́ẹ̀, àlàáfíà á wà láyé àti lọ́run. (Éfé. 1:​9, 10) Jèhófà á jẹ́ kó ṣe kedere pé òun nìkan lòun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣàkóso ayé àtọ̀run, ìṣàkóso Sátánì àti tèèyàn á forí ṣánpọ́n, Ọlọ́run á sì palẹ̀ wọn mọ́. Ìjọba Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi máa ṣàṣeyọrí. Torí pé àwọn kan máa jẹ́ adúróṣinṣin, á ṣe kedere pé àwọn èèyàn lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà kí wọ́n sì fara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀. (Aísá. 45:24) Ṣé wàá fẹ́ wà lára irú àwọn adúróṣinṣin bẹ́ẹ̀? Kò sí àní-àní pé wàá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Torí náà ká lè jẹ́ adúróṣinṣin, ó yẹ ká lóye bọ́rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó, ká má sì jẹ́ kóhun míì gbà wá lọ́kàn. w17.06 23 ¶4-5

Monday, September 23

Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.​—Òwe 17:17.

Àkókò tó máa ń gbà kí ẹ̀dùn ọkàn tó lọ lára ẹnì kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra. Torí náà, ká má ṣe fi lílọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ mọ sígbà tí àjálù náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀, táwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wà pẹ̀lú wọn, àmọ́ ká tún máa bẹ̀ wọ́n wò kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tí tẹbítọ̀rẹ́ ti pa dà sílé wọn. Orísun ìtùnú làwa Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ títí dìgbà tí wọ́n á gbé e kúrò lára. (1 Tẹs. 3:7) Ká rántí pé àròkàn ní í fa ẹkún àsun-ùndá. Torí náà, déètì kan nínú ọdún lè mú kẹ́ni téèyàn rẹ̀ kú rántí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ ẹ́, ó sì lè jẹ́ orin kan tẹ́ni náà fẹ́ràn tàbí fọ́tò rẹ̀, kódà ó lè jẹ́ òórùn lásán tàbí àwọn nǹkan míì. Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn méjèèjì ti jọ ń ṣe pa pọ̀, àmọ́ ní báyìí tó ku òun nìkan, ó lè ṣòro fún un láti ṣe àwọn nǹkan kan, bíi lílọ sí àpéjọ tàbí Ìrántí Ikú Kristi. Àmọ́ o, kì í ṣe irú àwọn àsìkò báyìí nìkan làwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nílò ìṣírí. w17.07 16 ¶17-19

Tuesday, September 24

Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.​—Fílí. 2:4.

Òótọ́ kan ni pé, tá a bá ń ronú nípa bá a ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́, ó lè mú ká gbọ́kàn kúrò lórí ẹ̀dùn ọkàn wa. Àwọn arábìnrin tó ti ṣègbéyàwó àtàwọn tí kò tíì ṣe bẹ́ẹ̀ máa ń láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere, tí wọ́n sì ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́. Bí wọ́n á ṣe bọlá fún Jèhófà tí wọ́n á sì ṣèfẹ́ rẹ̀ ló jẹ wọ́n lọ́kàn. Àwọn kan tiẹ̀ gbà pé iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ káwọn gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro àwọn, ó sì máa ń fún àwọn ní ìtùnú. Ká sòótọ́, gbogbo wa la máa pa kún ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ, tá a bá jẹ́ kí ire àwọn ará àti tàwọn tá à ń wàásù fún jẹ wá lọ́kàn. Àpẹẹrẹ àtàtà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ nínú èyí. Ó fi ara rẹ̀ wé “abiyamọ” torí pé ó máa ń ṣìkẹ́ àwọn ará ìjọ Tẹsalóníkà, ó sì tún dà bíi bàbá fún wọn. (1 Tẹs. 2:​7, 11, 12) Táwọn ọmọ bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run, wọ́n lè di orísun ìtùnú fáwọn tó wà nínú ìdílé wọn. Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn, tí wọ́n sì ń ṣèrànwọ́ fún wọn. Wọ́n tún lè jẹ́ orísun ìtùnú tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. w17.06 7 ¶13-14; 8 ¶17

Wednesday, September 25

Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo.​—Lúùkù 16:9.

Bá ò tilẹ̀ rídìí ọ̀rọ̀ yìí délẹ̀délẹ̀, ohun kan tó dájú ni pé akúṣẹ̀ẹ́ lèyí tó pọ̀ jù láyé nígbà tí ìwọ̀nba díẹ̀ sì ní owó tí ìrandíran wọn ò lè ná tán. Jésù mọ̀ pé bí ọrọ̀ ajé ṣe máa nira nìyẹn títí Ìjọba Ọlọ́run á fi dé. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ètò ìṣèlú, ẹ̀sìn èké àti ètò ìṣòwò tí Ìṣípayá 18:3 pè ní “àwọn olówò arìnrìn-àjò” jẹ́ apá kan ayé Sátánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn Ọlọ́run kì í lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣèlú tàbí ẹ̀sìn èké, kò sí bí ọ̀pọ̀ wa ṣe lè yẹra pátápátá fún ìṣòwò nínú ayé Sátánì yìí. Ó yẹ káwa Kristẹni ronú nípa ojú tá a fi ń wo ọ̀rọ̀ ìṣòwò ayé yìí, ká bi ara wa pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè lo àwọn ohun ìní mi lọ́nà táá fi hàn pé mo jólóòótọ́ sí Jèhófà? Kí ni mo lè ṣe tí mi ò fi ní tara bọ ọ̀rọ̀ ìṣòwò ayé yìí? Àwọn ìrírí wo làwa èèyàn Jèhófà ní tó fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá lásìkò tí nǹkan nira yìí?’ w17.07 7-8 ¶1-3

Thursday, September 26

Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé.​—Lúùkù 21:34.

Jésù mọ̀ pé àwọn nǹkan tó ń kó àníyàn báni máa pọ̀ gan-an nínú ayé yìí, á sì mú kí nǹkan nira. Nínú àpèjúwe kan tí Jésù sọ nípa afúnrúgbìn, ó sọ pé àwọn kan máa tẹ́wọ́ gba “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” wọ́n á sì tẹ̀ síwájú, àmọ́ tó bá yá “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” máa “fún ọ̀rọ̀ náà pa.” (Mát. 13:​19-22; Máàkù 4:19) Ẹ ò rí i pé téèyàn ò bá kíyè sára, ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu lè gbani lọ́kàn débi pé èèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí í dẹwọ́ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó yẹ káwa náà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Kristi gan-an, ká rí i pé iṣẹ́ ìwàásù tó gbé fún wa ló gbawájú láyé wa. Kí la lè ṣe tá ò fi ní dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà? Ó ṣe pàtàkì ká máa bi ara wa látìgbàdégbà pé: ‘Kí lohun tí mo fẹ́ràn jù gan-an? Ṣé àwọn nǹkan tara tí mò ń ṣe ló máa ń yá mi lára jù ni àbí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run?’ w17.05 23 ¶3-4

Friday, September 27

Ẹ sọ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn láti lóye. ​—1 Kọ́r. 14:9.

Táwọn tó ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì bá ń gbé níbi tó jìnnà sí ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn, ìjọ tó ń sọ èdè àdúgbò ibẹ̀ ni wọ́n máa lọ. (Sm. 146:9) Àmọ́, tí ìjọ tó ń sọ èdè ìbílẹ̀ wọn bá wà nítòsí, á dáa kí wọ́n fara balẹ̀ ronú lórí ìjọ tí wọ́n máa lọ. Olórí ìdílé ló máa ṣèpinnu yìí. Àmọ́, kó tó ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, kó fi í sádùúrà, kó sì jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀. (1 Kọ́r. 11:3) Àwọn òbí gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú ohun táwọn ọmọ wọn nílò jù. Bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa ni wọ́n ń sọ níjọ tí wọ́n ń lọ, kì í ṣe wákàtí mélòó kan tí wọ́n ń lò níbẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nìkan ló máa jẹ́ kí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn àwọn ọmọ wọn. Ká má tíì wá sọ pé kí wọ́n máa lọ síjọ tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbédè tí wọ́n ń sọ. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé èdè táwọn ọmọ wọn gbọ́ dáadáa ni wọ́n ń sọ nípàdé, wọ́n á lóye ohun tí wọ́n ń sọ ju báwọn òbí wọn ṣe rò lọ.​—1 Kọ́r. 14:11. w17.05 10 ¶10-11

Saturday, September 28

Nítorí tí àwọn ènìyàn náà fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn, ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà.​—Oníd. 5:2.

Ó yẹ kí kálukú wa bi ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé mo ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà táá jẹ́ kí n ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà? Bí mo bá ń ronú láti ṣí lọ sílùú tàbí orílẹ̀-èdè míì kí n lè rí tajé ṣe, ṣé mo ti ro ọ̀rọ̀ náà tàdúràtàdúrà? Ṣé mo ti ronú ìpalára tó máa ṣe fún ìdílé mi àti ìjọ?’ Jèhófà pọ́n àwa èèyàn lé ní ti pé ó fún wa láǹfààní láti kọ́wọ́ ti ìṣàkóso rẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀, torí náà tó o bá fara rẹ sábẹ́ àkóso Jèhófà, ṣe lò ń jẹ́ kí Sátánì mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Jèhófà lo wà. Ìgbàgbọ́ tó o ní àti bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin ló mú kó o yọ̀ǹda ara rẹ, èyí sì ń múnú Jèhófà dùn. (Òwe 23:​15, 16) Bó o ṣe ń kọ́wọ́ ti ìṣàkóso Jèhófà ń jẹ́ kó lè máa fún Sátánì lésì. (Òwe 27:11) Torí náà, bó o ṣe jẹ́ adúróṣinṣin, tó o sì ń ṣègbọràn, Jèhófà gbà pé ẹ̀bùn iyebíye lò ń fún òun, ìyẹn sì ń múnú rẹ̀ dùn gan-an. w17.04 32 ¶15-16

Sunday, September 29

Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti san án, nítorí pé kò sí níní inú dídùn sí àwọn arìndìn. Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.​—Oníw. 5:4.

Òfin Mósè sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà tàbí tí ó ṣe ìbúra kan . . . , kí ó má ṣẹ̀ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí ó jáde ní ẹnu rẹ̀ ni kí ó ṣe.” (Núm. 30:2) Nígbà tó yá, ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Sólómọ́nì sọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní. Jésù náà jẹ́ kó ṣe kedere pé ẹ̀jẹ́ jíjẹ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré nígbà tó sọ pé: “A sọ ọ́ fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ búra láìmúṣẹ, ṣùgbọ́n ìwọ gbọ́dọ̀ san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Jèhófà.’ ” (Mát. 5:33) Ó ṣe kedere pé kéèyàn jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run kì í ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré rárá. Ọwọ́ tá a bá fi mú ẹ̀jẹ́ wa lè mú kí Ọlọ́run fojúure wò wá tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Dáfídì sọ pé: ‘Ta ní lè gun orí òkè ńlá Jèhófà, ta sì ni ó lè dìde ní ibi mímọ́ rẹ̀? Ẹni tí kò búra ẹ̀tàn.’​—Sm. 24:​3, 4. w17.04 3-4 ¶3-4

Monday, September 30

Kò lo ahọ́n rẹ̀ ní fífọ̀rọ̀ èké bani jẹ́.​—Sm. 15:3.

Tí Kristẹni kan bá rò pé ẹnì kan ti hùwà àìdáa sóun, ó yẹ kó ṣọ́ra kó má lọ máa sọ̀rọ̀ náà kiri. A lè lọ bá àwọn alàgbà fún ìrànlọ́wọ́ tá a bá níṣòro, ó sì tún yẹ ká sọ fún wọn tẹ́nì kan nínú ìjọ bá hùwà àìtọ́ tó burú jáì. (Léf. 5:1) Síbẹ̀, tó bá jẹ́ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ kì í ṣe ìwà àìtọ́ tó burú jáì, a lè yanjú ọ̀rọ̀ náà láìpe ẹnikẹ́ni sí i títí kan àwọn alàgbà. (Mát. 5:​23, 24; 18:15) Tá a bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ìlànà Bíbélì ló yẹ ká fi yanjú irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Láwọn ìgbà míì, a lè wá rí i pé eni náà ò tiẹ̀ ṣàìdáa sí wa. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó pé a ò ba ẹni yẹn jẹ́ lójú àwọn míì! Ẹ rántí pé, yálà wọ́n hùwà àìdáa sí wa tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, tá a bá ń sọ̀rọ̀ náà kiri, ìyẹn ò ní yanjú ìṣòro náà. Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, tá a sì nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin wa, a ò ní ṣe irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀. w17.04 21 ¶14

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́