ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/06 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 10/06 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò jálẹ̀ oṣù náà. Bá a bá rẹ́ni tó fìfẹ́ hàn, ká fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la máa lò. Báwọn kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ká fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú mìíràn tó bá yẹ. December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Àwọn ìwé tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: A lè lo ìwé èyíkéyìí tá a tẹ̀ ṣáájú ọdún 1991. Ìwé míì tá a lè lò: Ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà!

◼ Níwọ̀n bí oṣù December ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí ni “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2007.” Ẹ tọ́jú rẹ̀ kẹ́ ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún.

◼ Ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan lóṣù January, a ó jíròrò fídíò tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ No Blood—Medicine Meets the Challenge, èyí tó dá lórí àwọn nǹkan míì tá a lè lò dípò ẹ̀jẹ̀. Bẹ́ ẹ bá fẹ́ àwo DVD rẹ̀ tàbí fídíò rẹ̀, kẹ́ ẹ béèrè nípasẹ̀ ìjọ yín bó bá ṣe lè yà tó.

◼ A ti pààrọ̀ àwọn nọ́ńbà tẹlifóònù tá à ń lò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Igieduma àti ọ́fíìsì tó wà ní Èkó. Àwọn nọ́ńbà tá à ń lò báyìí ní Igieduma ni: 052-202020, 052-202062 (FAX). Àwọn tá à ń lò ní Èkó ni 01-8990090, 01-8990091, 01-5820604 (VOICE AND FAX), 01-5820459 (VOICE AND FAX). Ẹnì kan á wà ní ọ́fíìsì láti máa gba gbogbo ìpè tó bá ń wọlé láàárín ọ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti aago méje ààbọ̀ àárọ̀ sí aago méjìlá ku ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àárọ̀ àti láti aago kan ọ̀sán sí aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́, bó bá jẹ́ ọjọ́ Saturday, ó máa jẹ́ láti aago méje ààbọ̀ àárọ̀ sí aago mọ́kànlá ààbọ̀ àárọ̀. Láwọn àkókò tó yàtọ̀ sí àwọn tá a mẹ́nu bà wọ̀nyí, tẹlifóònù fúnra rẹ̀ á sọ fẹ́ni tó bá pè pé kó tẹ nọ́ńbà ẹni tó bá fẹ́ bá sọ̀rọ̀ tàbí kó ní kí onítọ̀hún tẹ 0 láti lè ni kẹ́ni tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ràn òun lọ́wọ́. A tún ń rán yín létí pé, tẹ́ ẹ bá fẹ́ fi ìsọfúnni èyíkéyìí nípa ìjọ tó ẹ̀ka ọ́fíìsì létí, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ.

◼ A ó sọ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn fún sáà Ìṣe Ìrántí ti ọdún 2007 ní ọjọ́ Sunday, April 15, 2007. A ó ṣèfilọ̀ àkòrí àsọyé náà nígbà tó bá yá. Káwọn ìjọ tí wọ́n bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí àpéjọ àkànṣe lópin ọ̀sẹ̀ yẹn sọ àkànṣe àsọyé yìí ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Kí ìjọ kankan má ṣe sọ àkànṣe àsọyé yìí ṣáájú Sunday, April 15.

◼ Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Watch Tower Publications Index—2004—Gẹ̀ẹ́sì

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?—Onílẹ́tà Gàdàgbà—Gẹ̀ẹ́sì

◼ Àwọn Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? (kásẹ́ẹ̀tì márùn-ún ló wà nínú ẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

◼ Àwọn Àwo DVD Tuntun Tó Wà Lọ́wọ́:

Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Lórí Àwo DVD—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà

Ẹ Máa Lépa Ohun Tó Máa Gbórúkọ Ọlọ́run Ga—Lórí Àwo DVD—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà

Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?—Lórí Àwo DVD—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà

Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú —Lórí Àwo DVD—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà

Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà—Lórí Àwo DVD—Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Amẹ́ríkà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́