Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 13
Orin 174
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù October sílẹ̀. Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àbá tó wà lójú ìwé 8 nípa bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ October 1 àti Jí! October-December. Ó ti tó bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan báyìí táwọn ará ti ń lo àwọn ìwé ìròyìn yìí lóde ẹ̀rí, ní kí wọ́n sọ ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń lo àwọn ìwé ìròyìn yìí.
35 min: “Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣèpàdé.”a Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
Orin 216
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 20
Orin 113
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
20 min: Máa Bá A Nìṣó ní Jíjẹ́ Aláyọ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà. Àsọyé tó ń gbéni ró tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 1, 2005 ojú ìwé 24 àti 25 ìpínrọ̀ 11 sí 17. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà bọ̀ láti ọjọ́ tó ti pẹ́. Kí ló mú kí wọ́n máa bá a nìṣó láti máa láyọ̀ nígbà táwọn èèyàn kò fetí sí wọn?
20 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ November 1 àti Jí! October-December. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn ìwé ìròyìn yìí, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Níparí ọ̀rọ̀ rẹ, lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá lójú ìwé 8 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan.
Orin 148
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 27
Orin 30
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
30 min: “Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Ṣe Pàtàkì.”b Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
Orin 142
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 3
Orin 100
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù October sílẹ̀.
20 min: Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2009. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ jíròrò àwọn àyípadà tó ti bá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú àwùjọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìtọ́ni lórí Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú àkìbọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìjọba wa yìí. Pe àfiyèsí àwùjọ sí àwọn àyípadà tá a ṣe. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti wá ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá yàn fún wọn nílé ẹ̀kọ́, kí wọ́n máa múra sílẹ̀ láti dáhùn nígbà tá a bá ń bójú tó àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìmọ̀ràn tí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ ń fúnni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
15 min: Mú Kí “Ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” Rẹ Sunwọ̀n Sí I. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà míì tó tóótun sọ ohun márùn-ún tó ṣe pàtàkì téèyàn lè ṣe tó bá fẹ́ kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn, kó sì ṣàlàyé ṣókí lórí àwọn kókó náà, bó ṣe wà nínú Ilé Ìṣọ́ January 15, 2008, ojú ìwé 9 sí 12, ìpínrọ̀ 5 sí 18. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ti rí i pé àwọn kókó yìí ti ran àwọn lọ́wọ́ láti mú kí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́ni sunwọ̀n sí i.
Orin 91
[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.