Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 31
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 31
Orin 42 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 29 ìpínrọ̀ 16 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 299 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 9-11 (8 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Ìṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣ. 24:15.
10 min: Ǹjẹ́ Ò Ń Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I? Ìjíròrò. Sọ kókó pàtàkì tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2014 tá a fi ṣàlàyé ìdí tá a fi ṣe ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I.” Ní ṣókí, ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn kan lára ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí. Ní kí àwọn ará sọ ọ̀nà tí wọ́n gbà jàǹfààní nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n máa dìídì kíyè sí àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn sunwọ̀n sí i bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan tó ń jáde lóṣooṣù, kí wọ́n sì máa fi àwọn àbá tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí tá a pè ní “Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí” sílò.
10 min: Ṣé Ò Ń Rí Oúnjẹ Gbà “Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu”? Àsọyé tó dá lórí àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2014, ojú ìwé 3 sí 5. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa dáadáa.
10 min: Àwọn Àfojúsùn Tẹ̀mí Wo Ló Ní fún Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 2016? Ìjíròrò tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 118, ìpínrọ̀ 3. Ní kí àwọn tọkọtaya kan ṣe àṣefihàn kan. Àwọn méjèèjì ń jíròrò àfojúsùn tẹ̀mí tí wọ́n ní fún ọdún iṣẹ́ ìsìn tuntun.
Orin 10 àti Àdúrà