ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 July ojú ìwé 4-5
  • July 15-21

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July 15-21
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 July ojú ìwé 4-5

JULY 15-21

SÁÀMÙ 63-65

Orin 108 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. “Ìfẹ́ Rẹ Tí Kì Í Yẹ̀ Sàn Ju Ìyè”

(10 min.)

Kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ìyè lọ (Sm 63:3; w01 10/15 15-16 ¶17-18)

A máa túbọ̀ mọyì Jèhófà tá a bá ń ronú lórí bó ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa (Sm 63:6; w19.12 28 ¶4; w15 10/15 24 ¶7)

Tá a bá mọyì ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa, ìyẹn á jẹ́ kínú wa máa dùn bá a ṣe ń yìn ín (Sm 63:4, 5; w09 7/15 16 ¶6)

Àwòrán: Arábìnrin kan ń ka Bíbélì. 1. Inú ẹ̀ ń dùn bó ṣe ń bá arábìnrin mí ì ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù. 2. Ó ń dáhùn nípàdé.

OHUN TẸ́ Ẹ LÈ ṢE NÍGBÀ ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ: Ẹ sọ àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí yín.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 64:3—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró? (w07 11/15 15 ¶6)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 63:1–64:10 (th ẹ̀kọ́ 12)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni tó o fẹ́ wàásù fún ò gbọ́ èdè rẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. O ò ráyè wàásù títí ìjíròrò náà fi parí. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)

6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Fọgbọ́n wádìí ohun tó ń jẹ ẹni náà lọ́kàn, kó o sì béèrè bó o ṣe lè kàn sí i nígbà míì. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)

7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(4 min.) Àṣefihàn. ijwfq 51—Àkòrí: Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Máa Ń Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Ti Sọ Pé “Mi Ò Fẹ́ Gbọ́”? (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 154

8. Bá A Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run

(15 min.) Ìjíròrò.

‘Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀’ tí Jèhófà ní pọ̀ gidigidi. (Sm 86:15) Ọ̀rọ̀ náà ‘ìfẹ́ tí kì í yẹ̀’ túmọ̀ sí ìfẹ́ tí ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin àti adúrótini máa ń ní sáwọn èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ni Jèhófà nífẹ̀ẹ́, àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀ nìkan ló máa ń fi ‘ìfẹ́ tí kì í yẹ̀’ hàn sí. (Sm 33:18; 63:3; Jo 3:16; Iṣe 14:17) A lè fi hàn pé a mọyì ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ títí kan èyí tó sọ pé ká máa ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’—Mt 28:19; 1Jo 5:3.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń mú ká wàásù

    Apá kan nínú fídíò “Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.” Bàbá tó wà nínú fídíò yẹn sùn sórí àga lẹ́yìn tó dé láti ibi iṣẹ́.
  • tó bá rẹ̀ wá?

  • Apá kan nínú fídíò “Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.” Onílé kan tí inú ń bí pariwo mọ́ bàbá tó wà nínú fídíò náà àti ọmọ rẹ̀.
  • táwọn èèyàn bá ta kò wá?

  • Apá kan nínú fídíò “Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù.” Nínú fídíò yẹn, ìyá kan àti ọmọ ẹ̀ ń bá òṣìṣẹ́ ilé ìtajà kan sọ̀rọ̀.
  • lẹ́nu ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 12 ¶14-20

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 79 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́