ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 54 ojú ìwé 130-ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 1
  • Jèhófà Ní Sùúrù fún Jónà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ní Sùúrù fún Jónà
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Kọ́ Ìdí Tó Fi Yẹ Kó Jẹ́ Aláàánú
    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
  • Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Jona Kọ́ Nípa Àánú Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Jónà Àti Ẹja Ńlá
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 54 ojú ìwé 130-ojú ìwé 131 ìpínrọ̀ 1
Jónà ń rì sínú òkun, ẹja ńlá kan kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀

Ẹ̀KỌ́ 54

Jèhófà Ní Sùúrù fún Jónà

Ìgbà kan wà táwọn ará Ásíríà tó ń gbé nílùú Nínéfè ń hùwà tó burú gan-an. Jèhófà wá sọ fún wòlíì ẹ̀ tó ń jẹ́ Jónà pé kó lọ sí Nínéfè, kó sì kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n yíwà burúkú wọn pa dà. Àmọ́ kàkà kí Jónà lọ jíṣẹ́, ńṣe ló sá lọ síbòmíì. Ó lọ wọ ọkọ̀ ojú omi, ó sì forí lé ìlú kan tó ń jẹ́ Táṣíṣì.

Nígbà tí ọkọ̀ yìí ń lọ lójú omi, atẹ́gùn tó lágbára kan bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́, ẹ̀rù sì ba àwọn tó ń wa ọkọ̀ náà. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sáwọn òrìṣà wọn, wọ́n sì béèrè pé: ‘Kí ló dé tí nǹkan yìí fi ń ṣẹlẹ̀?’ Nígbà tó yá, Jónà sọ fún wọn pé: ‘Èmi ni mo fa gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Torí pé Jèhófà rán mi níṣẹ́ àmọ́ mo sá lọ. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ kí atẹ́gùn yìí dáwọ́ dúró, ẹ jù mí sínú òkun yìí.’ Àwọn tó ń wa ọkọ̀ ojú omi náà ò fẹ́ ju Jónà sínú òkun, àmọ́ ó sọ fún wọn pé kí wọ́n ju òun sínú omi náà. Nígbà tí wọ́n jù ú sínú òkun, atẹ́gùn tó lágbára náà wálẹ̀, kò sì dà wọ́n láàmú mọ́.

Jónà rò pé òun máa kú bí wọ́n ṣe ju òun sínú omi. Ṣùgbọ́n bó ṣe ń lọ sísàlẹ̀ nínú òkun náà ló tún ń fi ọkàn gbàdúrà sí Jèhófà. Jèhófà wá rán ẹja ńlá kan nínú òkun náà pé kó gbé Jónà mì, àmọ́ ẹja náà ò pa á jẹ. Nígbà tí Jónà dé inú ẹja náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: ‘Mo ṣèlérí pé gbogbo ohun tó o bá ní kí n ṣe ni màá ṣe.’ Jèhófà dá ẹ̀mí Jónà sí nínú ẹja náà fún ọjọ́ mẹ́ta, lẹ́yìn náà ó mú kí ẹja náà pọ Jónà sórí ilẹ̀ tó gbẹ.

Ní báyìí tí Jèhófà ti gba Jónà là, ṣé ó ṣì máa fẹ́ kó lọ sílùú Nínéfè? Bẹ́ẹ̀ ni. Jèhófà tún sọ fún Jónà pé kó lọ sí Nínéfè. Lọ́tẹ̀ yìí, Jónà ṣe ohun tí Jèhófà sọ. Ó lọ síbẹ̀, ó sì sọ fáwọn èèyàn burúkú náà pé: ‘Ní ogójì (40) ọjọ́ sí i, ìlú Nínéfè máa pa run.’ Bó ṣe sọ̀rọ̀ yìí tán, ẹ jẹ́ mọ̀ pé ńṣe làwọn ará Nínéfè yíwà burúkú wọn pa dà. Ọba ìlú tiẹ̀ sọ fáwọn ará ìlú pé: ‘Ẹ bẹ Ọlọ́run kẹ́ ẹ sì yí pa dà. Bóyá, ó lè ṣàánú wa, kó má pa wá.’ Nígbà tí Jèhófà rí i pé àwọn èèyàn náà ti yí pa dà, kò pa wọ́n run mọ́.

Jónà sún mọ́ ìtòsí ìlú Nínéfè

Ni inú bá bẹ̀rẹ̀ sí í bí Jónà pé Ọlọ́run ò pa ìlú náà run mọ́. Ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí ná, Jèhófà ní sùúrù fún Jónà, ó sì ṣàánú ẹ̀ nígbà tó sá lọ, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ṣùgbọ́n Jónà ò fẹ́ ṣàánú àwọn ará ìlú Nínéfè. Ó fìbínú lọ jókòó sábẹ́ ewéko akèrègbè kan níwájú ìlú náà, ó wá ṣu ẹnu pọ̀. Kò pẹ́ rárá tí ewéko náà fi gbẹ, èyí wá túbọ̀ múnú bí Jónà gan-an. Jèhófà wá sọ fún un pé: ‘Ò ń káàánú ewéko yìí torí pé ó gbẹ, àmọ́ o ò fẹ́ sàánú àwọn èèyàn ìlú Nínéfè. Mo káàánú wọn ni mi ò ṣe pa wọ́n run.’ Ẹ̀kọ́ wo ló wà níbẹ̀? Àwọn èèyàn ìlú Nínéfè ṣe pàtàkì ju igi lásán lọ.

“Jèhófà . . . ń mú sùúrù fún yín torí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.”​—2 Pétérù 3:9

Ìbéèrè: Ẹ̀kọ́ wo ni Jèhófà kọ́ Jónà? Kí làwa náà lè kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jónà?

Jónà 1:1–4:11

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́