Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti 1997
1 “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn.” (Orin Dá. 84:10, NW) Nígbà tí onísáàmù jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì Jèhófà, òun lè fòye mọ wíwàníbẹ̀ Ọlọ́run Olódùmarè. Nígbà tí orílẹ̀-èdè náà pé jọ fún àwọn ayẹyẹ ọdọọdún, tí àwọn olùjọsìn tòótọ́ sì kún Jerúsálẹ́mù fọ́fọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ìbákẹ́gbẹ́ aládùn bí wọ́n ti pé jọ pọ̀ ní àgbàlá tẹ́ńpìlì. A rán wọn létí ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé tí Jèhófà fi ìbùkún àti ojú rere rẹ̀ jíǹkí. Lọ́dọọdún, a ní àǹfààní láti bá ẹgbẹẹgbẹ̀rún arákùnrin àti arábìnrin wa ṣàjọpín ìmọ̀lára kan náà ti ìṣọ̀kan àti ìdùnnú. Ní àkókò wa, àwọn àpéjọpọ̀ ọdọọdún jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí Jèhófà fi ń kó àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ pọ̀ fún ìtọ́ni àti ìbákẹ́gbẹ́.
2 Bíbójútó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn Jèhófà tí ń gbé nínú Jerúsálẹ́mù àti lẹ́yìn òde rẹ̀ nígbà àwọn ayẹyẹ náà ń béèrè ìṣètòjọ. Pípa ìwàlétòlétò àti àlàáfíà mọ́ ṣeé ṣe kí ó béèrè fún pípèsè ìtọ́ni nípa ilé gbígbé, àwọn àkókò ìpàdé, àti àwọn ìṣètò míràn. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ti kan ìjọsìn tòótọ́ tí wọ́n ń ṣe, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò fi ìdùnnú tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni wọ̀nyí.—Orin Dá. 42:4; 122:1.
3 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún arákùnrin ti lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá mẹ́wàá wákàtí láti ṣètò àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ní àpéjọpọ̀ àti láti ṣètò ilé gbígbé ní ìlú àpéjọpọ̀ 23. Àwọn arákùnrin wọ̀nyí bá Ọ́fíìsì Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Àpéjọpọ̀ ti Society ṣiṣẹ́ pẹ́kípẹ́kí ní ṣíṣe kòkáárí ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ṣíṣe àpéjọpọ̀. Àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè má mọ iye àkókò, ìsapá, àti ìnáwó tí àwọn àpéjọpọ̀ ọdọọdún wa ń gbà, ṣùgbọ́n ó dájú pé gbogbo wa mọrírì ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ń fi hàn, àbí a kò mọrírì rẹ̀?
4 Bí ìmúrasílẹ̀ ti ń bá a nìṣó fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997 wa, a ní àwọn kókó kan tí ń fẹ́ àfiyèsí onínúure àti àgbéyẹ̀wò onírònújinlẹ̀ yín. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín yóò fi ìmọrírì ẹnì kọ̀ọ̀kan yín fún gbogbo ètò tí a ṣe nítorí yín hàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti jíròrò díẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ṣáájú, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa mọ ẹrù iṣẹ́ tí a ní níwájú Jèhófà láti ṣètìlẹ́yìn fún ìṣètò àpéjọpọ̀ wa, ní kedere.
5 Àwọn Ìtọ́ni fún Gbígba Ilé Gbígbé: Àwa yóò sakun láti pèsè iye àwọn fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé tí ó pọ̀ tó fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé kọ̀ọ̀kan tí a fi sílẹ̀ ni a kọ ọ̀rọ̀ kún lọ́nà tí ó yẹ. MÁ ṢE kọ kìkì iye àwọn akéde tí wọ́n nílò ilé gbígbé, irú bí “50 akéde,” sínú àlàfo tí a ní láti kọ orúkọ àwọn wọ̀nyí sí. A gbọ́dọ̀ kọ gbogbo ìsọfúnni nigín-nigín kí ó sì ṣeé kà. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni ní ti orúkọ, ọjọ́ orí, bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin, àti bóyá ẹni náà tí ń béèrè fún ilé gbígbé jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Fi àwọn ọmọ kún àkọsílẹ̀ náà. Ní ìgbà kan rí, kìkì orúkọ àwọn àgbàlagbà ni àwọn ìjọ kan kọ sílẹ̀. Èyí mú kí àwọn ìṣètò fún ilé gbígbé ṣòro gan-an. Bí o bá nílò àyè sí i ju èyí tí a pèsè lórí fọ́ọ̀mù náà, lo àfikún abala ìwé. Bí orúkọ tí ó ju ti ẹnì kan lọ bá wà lórí fọ́ọ̀mù náà, jọ̀wọ́ fi ipò ìbátan tí ó wà láàárín àwọn wọnnì tí ń béèrè fún ilé gbígbé hàn ní àlàfo ìlà tí ó yẹ. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé náà ni a kọ ọ̀rọ̀ kún lọ́nà pípéye ṣáájú kí ó tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé Àpéjọpọ̀ náà.
6 Lọ́dọọdún, a máa ń rọ àwọn ará láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé Àpéjọpọ̀. Ó kéré tán, ohun méjì ni a máa ń ṣàṣeparí rẹ̀ nípa kíkọbi ara sí ìtọ́sọ́nà yí:
7 Ó ń dín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ ní ìnáwó kù: Nígbà tí a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Society, ó máa ń dín àwọn ará wa ní owó ilé kù. Dípò kí àṣẹ́kù owó wa máa bọ́ sápò àwọn hòtẹ́ẹ̀lì tàbí sápò àwọn onílé, a lè lò ó lọ́nà tí ó sàn jù láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé wa àti fún iṣẹ́ kárí ayé. Àní bí àwa fúnra wa bá tilẹ̀ lè gba àwọn ilé gbígbé tí owó wọn wọ́n pàápàá, ó yẹ kí a ṣètìlẹ́yìn fún ìsapá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Èyí jẹ́ ẹ̀mí àníyàn fún àwọn ẹlòmíràn tí a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Jòhánù Kíní 3:17 àti ìlànà tí ń bẹ nínú Kọ́ríńtì Kíní 10:24.
8 Ó ń fi ṣíṣègbọràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà Society hàn: Kókó yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olórí àníyàn wa. Hébérù 13:17 wí pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn wọnnì tí ń mú ipò iwájú láàárín yín kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́mìí ìjuwọ́sílẹ̀ ní ìtẹríba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn wọnnì tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú [ìdùnnú] kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò fa ìfarapa bá yín.” Bí àwọn arákùnrin wa ti ń ṣe ọ̀pọ̀ ètò fún àpéjọpọ̀ àgbègbè wa, a fẹ́ kí wọ́n nímọ̀lára pé a tì wọ́n lẹ́yìn ní kíkún. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kìkì fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta lọ́dọọdún ni a máa ń béèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa lórí ọ̀ràn yí, ọ̀nà dáradára kan nìyí láti ti ìsapá wọn lẹ́yìn. Àní bí yíyàn wa bá yàtọ̀, àpẹẹrẹ rere wa, tí àwọn arákùnrin wa àti ayé ń wò, ń gbé ẹ̀mí ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ìtìlẹ́yìn lárugẹ.—Fílíp. 2:1-4.
9 Àwọn Àkànṣe Àìní: Ìpèsè yí wà fún kìkì àwọn tí ó nílò àkànṣe ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe ètò tí ó jẹ mọ́ àpéjọpọ̀, ní pàtàkì ètò ilé gbígbé, nígbà àpéjọpọ̀. Wọ́n tún lè nílò ìrànwọ́ ní àwọn ọ̀nà míràn, èyí tí ó sinmi lórí àyíká ipò olúkúlùkù wọn. Kìkì àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà àwòfiṣàpẹẹrẹ, títí kan àwọn ọmọ wọn tí wọ́n mọ̀wàáhù, tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ fọwọ́ sí nìkan ni wọ́n tóótun fún ìrànwọ́ lábẹ́ ètò Àìní Àkànṣe. Kí ìjọ tí àwọn tí ó ní àkànṣe àìní ti ń lọ sí ìpàdé ṣètò láti bójú tó àwọn ìṣètò míràn, dípò gbígbé iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe yìí karí àjọ tí ń ṣàbójútó àpéjọpọ̀. Àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn tí wọ́n mọ̀ nípa àyíká ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan lè fi ìfẹ́ nawọ́ ìrànlọ́wọ́. Èyí sábà máa ń béèrè pé kí àwọn akéde gbé àìní àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera, àti bóyá àwọn mìíràn, yẹ̀ wò. Àwọn akéde lè nawọ́ ìrànwọ́ nípa gbígbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dání pẹ̀lú wọn tàbí nípa bíbójú tó àìní wọn ní àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn.—Ják. 2:15-17; 1 Jòh. 3:17, 18.
10 Àmọ́ ṣáá o, Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé yóò sakun láti pèsè àwọn yàrá ilé gbígbé tí ó bójú mu fún àwọn akéde tí wọ́n ní àkànṣe àìní bí àwọn tí ó wà nínú ìjọ kò bá lè ṣètìlẹ́yìn fún wọn. Àwọn akéde wọ̀nyí lè bá akọ̀wé ìjọ jíròrò ipò wọn. Akọ̀wé ní láti bá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀ láti rí i bí ó bá ṣeé ṣe fún ìjọ láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni wọ̀nyí láti bójú tó yàrá ilé gbígbé tiwọn. Bí ìjọ kò bá lè ṣètìlẹ́yìn tí a nílò, akọ̀wé lè fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, lórí èyí tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ÀKÀNṢE ÀÌNÍ” sí lókè gàdàgbà gàdàgbà, ní ojú ìwé àkọ́kọ́. Kìkì àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní ni kí ó kọ ọ̀rọ̀ kún inú fọ́ọ̀mù tí a sàmì sí lọ́nà àkànṣe yìí. Ẹni tí ń ṣèbéèrè náà ni yóò kọ ọ̀rọ̀ kún un. Ó ní láti dá a pa dà fún akọ̀wé, tí yóò rí sí i pé a kọ ọ̀rọ̀ kún un, pé ó péye, tí yóò sì rí ẹ̀rí àrídájú àwọn ipò àyíká tí ó mú ẹni náà tóótun fún irú ìgbéyẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Akọ̀wé ní láti ṢÀLÀYÉ KÚLẸ̀KÚLẸ̀ nípa àwọn ipò àyíká náà sínú àlàfo tí ó wà ní òdì kejì fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo èyí ni a ní láti ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò àpéjọpọ̀ náà. Lẹ́yìn náà ni akọ̀wé yóò fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ẹni náà tí ń ṣèbéèrè yí ni a óò sọ fún ní tààràtà nípa ilé gbígbé náà.
11 Àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní KÒ gbọ́dọ̀ lọ sí àpéjọpọ̀ kí wọ́n sì béèrè fún yàrá nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, nítorí pé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé gbọ́dọ̀ rí ẹ̀rí àrídájú láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
12 Lílọ sí Àpéjọpọ̀ Míràn: Ìjọ kọ̀ọ̀kan ni a yàn sí àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọn jù lọ. Ní sísinmi lórí iye àwọn akéde tí a yàn sí àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan, Society díwọ̀n iye ènìyàn tí yóò pésẹ̀ láti lè ṣètò fún ìjókòó, ilé gbígbé, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó tó. Ṣùgbọ́n, fún ìdí rere, bí ìwọ yóò bá lọ sí àpéjọpọ̀ kan tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a yàn ọ́ sí, tí o sì nílò ilé gbígbé, akọ̀wé ìjọ lè fún ọ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé. O lè kọ̀wé kún un, kí o sì jẹ́ kí akọ̀wé fọwọ́ sí i, ṣáájú kí o tó fi ránṣẹ́ sí àpéjọpọ̀ tí o fẹ́ láti lọ.
13 Ìparí: Ó hàn gbangba sí gbogbo wa pé Jèhófà ń ti ìṣètò àwọn àpéjọpọ̀ ọdọọdún lẹ́yìn. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin tí ń rìnrìn àjò lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ti nílò yàrá ilé gbígbé, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò kúnjú àwọn àìní wọ̀nyí tẹ́rùntẹ́rùn. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ti ní ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́ wa, ó yẹ kí a fi ìdùnnú tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí a pèsè. Fífẹ̀ríhàn pé a “jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ” ń fi wá sójú ìlà fún gbígba àwọn ìbùkún títóbi lọ́lá tí ń dúró de àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́.—Lúùk. 16:10.
14 Aísáyà 33:20 wí pé: “Wo Síónì, ìlú àjọ àfiyèsí wa.” A wulẹ̀ lè ronú wòye ogunlọ́gọ̀ aláyọ̀ tí wọ́n máa ń kún Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì máa ń fi ìmúratán dáhùn pa dà sí àṣẹ Jèhófà láti “máa yọ̀ ní tòótọ́.” (Diu. 16:15) Àwọn àpéjọpọ̀ ọdọọdún wa ń fún wa ní àǹfààní títóbi lọ́lá láti gba ìtọ́ni àtọ̀runwá sínú, kí a sì gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ ọlọ́yàyà ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Ǹjẹ́ kí Jèhófà bù kún àwọn ìsapá rẹ bí o ti ń múra sílẹ̀ láti lọ sí ọ̀wọ́ àpéjọpọ̀ àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997!
[Àkíyèsí fún Ẹgbẹ́ Àwọn Alàgbà: Bí ẹ bá ti rí àkìbọnú yìí gbà, ẹ jọ̀wọ́ ṣèfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ó tẹ̀ lé e nípa ibi àpéjọpọ̀ àti déètì tí Society yàn fún ìjọ yín. Yóò dára láti fàlà sábẹ́ ìlú àpéjọpọ̀ àti déètì tí a yàn fún ìjọ yín, kí ẹ sì lẹ apá yẹn nínú àkìbọnú mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.
Akọ̀wé ìjọ ni kí ó bójú tó àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá tan mọ́ àpéjọpọ̀ àti àwọn ìfilọ̀ ní àwọn ìpàdé ọjọ́ iwájú. Ó dára kí gbogbo alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún láti rí i dájú pé àwọn ohun tí ó ní ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ náà ni a bójú tó ní kánmọ́kánmọ́, pẹ̀lú ìtara ọkàn, àti lọ́nà tí ó gbéṣẹ́.]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday
9:20 òwúrọ̀ -4:40 ìrọ̀lẹ́
Saturday
9:00 òwúrọ̀ -4:20 ìrọ̀lẹ́
Sunday
9:00 òwúrọ̀ -3:20 ìrọ̀lẹ́