Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti 1998
1 Lọ́dọọdún, àwọn olùjọsìn Jèhófà lónìí jákèjádò ilẹ̀ ayé máa ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún kíkórajọ rẹpẹtẹ ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè. Nínú èyí, wọ́n ń fi ẹ̀mí àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì hàn, tí wọ́n fi ìdùnnú kọ àwọn ọ̀rọ̀ Sáàmù 122 lórin nígbà tí wọ́n ń lọ sí Jerúsálẹ́mù láti jọ́sìn Jèhófà. Ẹsẹ 1 nínú Sáàmù yẹn kà pé: “Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé: ‘Jẹ́ kí a lọ sí ilé Jèhófà.’” Ní irú àwọn àkókò yẹn, a tún rí ẹ̀rí tí ń pọ̀ sí i pé ọ̀rọ̀ Aísáyà 2:2, 3 tí a mí sí ń ní ìmúṣẹ.
2 Lọ́dún yìí, a ní ìdí pàtàkì láti yọ̀ nítorí adùn jíjẹ́ kárí ayé tí àwọn àyànṣaṣojú láti àwọn orílẹ̀-èdè yíká ilẹ̀ ayé tí wọn yóò pésẹ̀ sí díẹ̀ nínú àwọn àpéjọpọ̀ yóò fi kún un. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ ní ibi àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan yóò gbé ìrírí láti inú pápá àti ìròyìn nípa ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní àwọn ilẹ̀ mìíràn jáde lákànṣe.
3 Àmọ́ ṣáá o, kìkì àwọn ìjọ tí a yàn tí wọ́n wà ní àgbègbè àwọn ibi àpéjọpọ̀ àgbáyé ni yóò lè lọ sí àwọn ìkórajọ wọ̀nyẹn. Ó ṣe kókó pé kí gbogbo wa bọ̀wọ̀ fún ààlà yìí kí a lè ṣe gbogbo àpéjọpọ̀ lọ́nà tí ó wà létòlétò. Ní gbogbo àpéjọpọ̀ àgbègbè, a óò rí adùn jíjẹ́ kárí ayé nínú àwọn apá ìtòlẹ́sẹẹsẹ àti ìròyìn, títí kan wíwà níbẹ̀ àwọn míṣọ́nnárì tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n wá.
4 Bí ìmúrasílẹ̀ ti ń bá a nìṣó fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” wa ti 1998, a óò fẹ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò ìsọfúnni díẹ̀ tí ẹ óò nílò kí ẹ lè gba ilé ibùwọ̀ fún àpéjọpọ̀ yìí. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ yóò fi ìmọrírì tí ẹ ní lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fún gbogbo ìṣètò tí a ṣe nítorí yín hàn.
5 Àwọn Ìtọ́ni fún Gbígba Ilé Ibùwọ̀: A óò sakun láti pèsè iye àwọn fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀ tí ó pọ̀ tó fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a fi sílẹ̀ ni a kọ ọ̀rọ̀ kún lọ́nà tí ó yẹ. MÁ ṢE kọ kìkì iye àwọn akéde tí wọ́n nílò ilé ibùwọ̀, irú bí “50 akéde,” sínú àlàfo tí ó yẹ kí a kọ orúkọ àwọn wọ̀nyí sí. A gbọ́dọ̀ kọ gbogbo ìsọfúnni nigín-nigín kí ó sì ṣeé kà. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni ní ti orúkọ, ọjọ́ orí, bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin, àti bóyá ẹni náà tí ń béèrè fún ilé ibùwọ̀ jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Fi àwọn ọmọ kún àkọsílẹ̀ náà. Ní ìgbà kan rí, kìkì orúkọ àwọn àgbàlagbà ni àwọn ìjọ kan kọ sílẹ̀. Èyí mú kí àwọn ìṣètò fún ilé ibùwọ̀ ṣòro gan-an. Bí o bá nílò àyè sí i ju èyí tí a pèsè lórí fọ́ọ̀mù náà, lo àfikún abala ìwé. Bí orúkọ tí ó ju ti ẹnì kan lọ bá wà lórí fọ́ọ̀mù náà, jọ̀wọ́ fi ipò ìbátan tí ó wà láàárín àwọn tí ń béèrè ilé ibùwọ̀ hàn ní àlàfo ìlà tí ó yẹ. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀ náà ni a kọ ọ̀rọ̀ kún lọ́nà pípéye ṣáájú kí ó tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ Àpéjọpọ̀ náà.
6 Lọ́dọọdún, a máa ń rọ àwọn ará láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ Àpéjọpọ̀. Ó kéré tán, ohun méjì ni a máa ń ṣàṣeparí rẹ̀ nípa kíkọbi ara sí ìtọ́sọ́nà yìí:
7 Ó ń dín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní ìnáwó kù: Nígbà tí a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Society, ó máa ń dín àwọn ará wa ní owó ilé kù. Dípò kí àṣẹ́kù owó wa máa bọ́ sápò àwọn onílé, a lè lò ó lọ́nà tí ó sàn jù láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àti fún iṣẹ́ kárí ayé. Àní bí àwa fúnra wa bá tilẹ̀ lè gba àwọn ilé ibùwọ̀ tí owó wọn wọ́n pàápàá, ó yẹ kí a ṣètìlẹ́yìn fún ìsapá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀. Ẹ̀mí àníyàn fún àwọn ẹlòmíràn yìí ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú 1 Jòhánù 3:17, òun sì ni ìlànà tí ó wà lẹ́yìn 1 Kọ́ríńtì 10:24.
8 Ó ń fi ṣíṣègbọràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà Society hàn: Kókó yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olórí àníyàn wa. Hébérù 13:17 wí pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” Bí àwọn arákùnrin wa ti ń ṣe ọ̀pọ̀ ètò fún àpéjọpọ̀ àgbègbè wa, a fẹ́ kí wọ́n nímọ̀lára pé a tì wọ́n lẹ́yìn ní kíkún. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kìkì fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta lọ́dọọdún ni a máa ń béèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa lórí ọ̀ràn yìí, ọ̀nà dáradára kan ni ó jẹ́ láti ti ìsapá wọn lẹ́yìn. Àní bí yíyàn wa bá yàtọ̀, àpẹẹrẹ rere wa, tí àwọn arákùnrin wa àti ayé ń wò, ń gbé ẹ̀mí ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ìtìlẹ́yìn lárugẹ.—Fílí. 2:1-4.
9 Àwọn Àkànṣe Àìní: Ìpèsè yìí wà fún kìkì àwọn tí ó nílò àkànṣe ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe ètò tí ó jẹ mọ́ àpéjọpọ̀ wọn, ní pàtàkì ètò ilé ibùwọ̀, nígbà àpéjọpọ̀. Wọ́n tún lè nílò ìrànwọ́ ní àwọn ọ̀nà mìíràn, èyí tí ó sinmi lórí àyíká ipò olúkúlùkù wọn. Kìkì àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà àwòfiṣàpẹẹrẹ, títí kan àwọn ọmọ wọn tí wọ́n mọ̀wàáhù, tí wọ́n ní àkànṣe àìní tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sì fọwọ́ sí nìkan ni wọ́n tóótun fún ìrànwọ́ lábẹ́ ètò Àkànṣe Àìní. Kí ìjọ tí àwọn tí ó ní àkànṣe àìní ti ń lọ sí ìpàdé ṣètò láti bójú tó àwọn ìṣètò yòókù lórí àwọn tí ó ní àìní àkànṣe dípò gbígbé iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe yìí karí àjọ tí ń ṣàbójútó àpéjọpọ̀. Àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn tí wọ́n mọ̀ nípa àyíká ipò ẹnì náà lè fi ìfẹ́ nawọ́ ìrànlọ́wọ́. Èyí sábà máa ń béèrè pé kí àwọn akéde gbé àìní àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera, àti bóyá àwọn mìíràn, yẹ̀ wò. Àwọn akéde lè nawọ́ ìrànwọ́ nípa gbígbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dání pẹ̀lú wọn tàbí nípa bíbójútó àìní wọn ní àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn.—Ják. 2:15-17; 1 Jòh. 3:17, 18.
10 Àmọ́ ṣáá o, Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ yóò sakun láti pèsè àwọn yàrá ibùwọ̀ tí ó bójú mu fún àwọn akéde tí wọ́n ní àkànṣe àìní bí àwọn tí ó wà nínú ìjọ kò bá lè ṣètìlẹ́yìn fún wọn. Àwọn akéde wọ̀nyí lè bá akọ̀wé ìjọ jíròrò ipò wọn. Kí akọ̀wé bá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bí ó bá ṣeé ṣe fún ìjọ láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni wọ̀nyí láti bójú tó yàrá ibùwọ̀ tiwọn. Bí ìjọ kò bá lè ṣètìlẹ́yìn tí a nílò, akọ̀wé lè fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀, lórí èyí tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ÀKÀNṢE ÀÌNÍ” sí lókè gàdàgbà, ní ojú ìwé àkọ́kọ́. Kìkì àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní ni kí ó kọ ọ̀rọ̀ kún inú fọ́ọ̀mù tí a sàmì sí lọ́nà àkànṣe yìí. Ẹni tí ń ṣèbéèrè náà ni kí ó kọ ọ̀rọ̀ kún un. Kí ó dá a padà fún akọ̀wé, tí yóò rí sí i pé a kọ ọ̀rọ̀ kún un, pé ó péye, tí yóò sì rí ẹ̀rí àrídájú àwọn àyíká ipò tí ó mú ẹni náà tóótun fún irú ìgbéyẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Akọ̀wé ní láti ṢÀLÀYÉ KÚLẸ̀KÚLẸ̀ nípa àwọn àyíká ipò náà sínú àlàfo tí ó wà ní òdì kejì fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo èyí ni a ní láti ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò àpéjọpọ̀ náà. Lẹ́yìn náà ni akọ̀wé yóò fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀. Ẹni náà tí ń ṣèbéèrè yìí ni a óò sọ fún ní tààràtà nípa ilé ibùwọ̀ náà.
11 Àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní KÒ GBỌ́DỌ̀ lọ béèrè fún yàrá nígbà tí wọ́n bá dé àpéjọpọ̀, nítorí pé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ gbọ́dọ̀ rí ẹ̀rí àrídájú láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
12 Lílọ sí Àpéjọpọ̀ Mìíràn: Ìjọ kọ̀ọ̀kan ni a yàn sí àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọn jù lọ. Ní sísinmi lórí iye àwọn akéde tí a yàn sí àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan, Society díwọ̀n iye ènìyàn tí yóò pésẹ̀ láti lè ṣètò fún ìjókòó, ilé ibùwọ̀, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó tó. Ṣùgbọ́n, fún ìdí rere, bí ìwọ bá fẹ́ lọ sí àpéjọpọ̀ kan tí ó yàtọ̀ sí èyí tí a yàn ọ́ sí, tí o sì nílò ilé ibùwọ̀, akọ̀wé ìjọ lè fún ọ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀. O lè kọ̀wé kún un, kí o sì jẹ́ kí akọ̀wé fọwọ́ sí i, ṣáájú kí o tó fi ránṣẹ́ sí àpéjọpọ̀ tí o fẹ́ láti lọ.
13 Máa Tọ́jú Owó fún Àpéjọpọ̀ Náà: Ní àfikún sí àwọn ìṣètò yòókù, ÌSINSÌNYÍ ni àkókò láti bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú owó fún àpéjọpọ̀ àgbègbè. Àwọn kan jìnnà díẹ̀ sí ibi àpéjọpọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn kan ní ìdílé ńlá. Fún àwọn wọ̀nyí àti fún gbogbo wa, a ń fẹ́ owó fún ṣíṣètọrẹ, ọkọ̀, oúnjẹ nígbà àpéjọpọ̀, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, títí kan àwọn ìtẹ̀jáde tuntun, àti àwọn ohun mìíràn tí a kò ronú tẹ́lẹ̀. Ó yẹ kí àwọn tí wọ́n ní ìdílé ńlá wéwèé ṣáájú kí wọ́n sì tọ́jú owó tí ó tó kí gbogbo ìdílé lè lọ sí àpéjọpọ̀ náà. Ọ̀nà kan tí ó gbéṣẹ́ lè jẹ́ nípa fífojú díwọ̀n àròpọ̀ iye owó tí a nílò. Ó lọ́gbọ́n nínú láti ṣírò pé owó nǹkan lè ròkè nígbà tí o bá ń fojú díwọ̀n ìnáwó. Fi àròpọ̀ iye oṣù tí ó wà láàárín ìsinsìnyí àti déètì àpéjọpọ̀ àgbègbè yín pín iye owó tí o fojú díwọ̀n. Iye owó tí o ní láti máa fi pa mọ́ lóṣooṣù nìyí. Lóṣooṣù, sọ ọ́ di dandan láti kọ́kọ́ yọ iye owó yìí sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí owó àpéjọpọ̀. O lè fi èyí pa mọ́ sínú àpótí kékeré kan tàbí sínú àpò ìwé. Ṣùgbọ́n, o lè pín iye owó tí ó yẹ kí o máa fi pa mọ́ lóṣooṣù sí ọ̀nà mẹ́rin kí o sì máa tọ́jú rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé kí o má ṣe dúró di ìgbà tí àkókò àpéjọpọ̀ bá ku oṣù kan tàbí méjì kí o tó máa gbìyànjú láti kówó jọ fún ìrìn àjò ọdọọdún tí a máa ń ṣe déédéé yìí.—Òwe 21:5.
14 Ìparí: Ìròyìn tí a gbọ́ láti àwọn àpéjọpọ̀ fi hàn pé ó yẹ kí a gbóríyìn fún ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin fún fífi àwọn ànímọ́ tí ó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu hàn. Ìròyìn kan sọ pé: “Àpéjọpọ̀ náà wà létòlétò, ó sì lálàáfíà, àwọn arákùnrin àti arábìnrin sì túbọ̀ fún àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí ní àfiyèsí ju àwọn nǹkan ti ara. . . . Lákòókò ìjókòó, àwọn àwùjọ olùgbọ́ tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ.” Ẹni tí ó ni ilé ẹ̀kọ́ kan tí àwọn alápèéjọpọ̀ dé sí sọ pé: “Mo máa ń gbọ́ pé ènìyàn mímọ́ ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n n kò fiyè sí i. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, èmi fúnra mi ti rí i. Orí mi wú láti rí i pé wọ́n mú kí àyíká ilé ẹ̀kọ́ mi mọ́ tónítóní, wọn kò yàgbẹ́ káàkiri ilẹ̀. Ẹ lómìnira láti lo ilé ẹ̀kọ́ yìí nígbàkigbà tí ẹ bá ń ṣe àwọn àpéjọpọ̀ yín.” Àwọn gbólóhùn bí ìwọ̀nyí dára láti gbọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ìwà àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó fa àwọn gbólóhùn wọ̀nyí ń mú inú Jèhófà dùn dájúdájú.
15 Society rí ọ̀pọ̀ lẹ́tà gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ń fi ìmọrírì wọn hàn fún àwọn ètò tí a ṣe nítorí wọn. Arákùnrin kan kọ̀wé pé: “Ẹ ṣeun púpọ̀ . . . Èyí jẹ́ nítorí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta ‘Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ tí èmi fúnra mi gbádùn. . . . Ẹ ṣeun gan-an ni fún bí ẹ ṣe ṣètò àpéjọpọ̀ náà dáadáa.” Arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún gbogbo àwọn arákùnrin mi tí wọ́n kópa nínú ìṣètò ilé ibùwọ̀. Èmi àti ọkọ mi mọrírì owó ilé tí ó dín kù náà, bí ó ti jẹ́ pé ẹnì kan nínú wa ní ń pawó wọlé kí n lè máa ṣe aṣáájú ọ̀nà nìṣó. Àwọn Ìṣètò wọ̀nyí ràn wá lọ́wọ́ láti jàǹfààní púpọ̀ sí i láti inú àpéjọpọ̀ náà.”
16 Ó ṣe kedere sí gbogbo wa pé Jèhófà ń ti ìṣètò àwọn àpéjọpọ̀ ọdọọdún lẹ́yìn. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ará tí ń rìnrìn àjò lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ti nílò ibùgbé, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò pèsè fún àìní wọ̀nyí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹ̀lú. Fífi ẹ̀rí hàn pé a jẹ́ “olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ” fi wa sójú ọ̀nà fún gbígba àwọn ìbùkún ńláǹlà tí ń dúró de àwọn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́.—Lúùkù 16:10.
[Àkíyèsí fún Ẹgbẹ́ Àwọn Alàgbà: Bí ẹ bá ti rí àkìbọnú yìí gbà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣèfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí ó tẹ̀ lé e nípa ibi àpéjọpọ̀ àti déètì tí Society yàn fún ìjọ yín. Yóò dára kí ẹ fàlà sábẹ́ ìlú àpéjọpọ̀ àti déètì tí a yàn fún ìjọ yín, kí ẹ sì lẹ apá yẹn nínú àkìbọnú mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.
Akọ̀wé ìjọ ni kí ó bójú tó àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ àti àwọn ìfilọ̀ ní àwọn ìpàdé ọjọ́ iwájú. Ó dára kí gbogbo alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún láti rí i dájú pé a bójú tó àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ náà ní kánmọ́kánmọ́, pẹ̀lú ìtara ọkàn, àti lọ́nà tí ó gbéṣẹ́.]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday
9:20 òwúrọ̀–4:50 ìrọ̀lẹ́
Saturday
9:00 òwúrọ̀–4:30 ìrọ̀lẹ́
Sunday
9:00 òwúrọ̀–3:30 ìrọ̀lẹ́