28 Nígbà tí àwọn oníṣòwò tí wọ́n jẹ́ ọmọ Mídíánì+ ń kọjá lọ, wọ́n fa Jósẹ́fù jáde látinú kòtò omi náà, wọ́n sì tà á fún àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì ní ogún (20) ẹyọ fàdákà.+ Ni àwọn ọkùnrin yìí bá mú Jósẹ́fù lọ sí Íjíbítì.
35 Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń gbìyànjú láti tù ú nínú, àmọ́ kò gbà, ó ń sọ pé: “Màá ṣọ̀fọ̀ ọmọ mi wọnú Isà Òkú!”*+ Bàbá rẹ̀ sì ń sunkún torí rẹ̀.