38 Àmọ́ ó sọ pé: “Ọmọ mi ò ní bá yín lọ, torí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ló sì ṣẹ́ kù.+ Bí jàǹbá bá lọ ṣe é ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, ó dájú pé ẹ ó mú kí n ṣọ̀fọ̀+ wọnú Isà Òkú*+ pẹ̀lú ewú orí mi.”
27 Bàbá mi tó jẹ́ ẹrú rẹ wá sọ fún wa pé, ‘Ẹ mọ̀ dáadáa pé ọmọ méjì péré ni ìyàwó mi bí fún mi.+28 Àmọ́ ọ̀kan nínu wọn ti fi mí sílẹ̀, mo sì sọ pé: “Ó dájú pé ẹranko kan ti fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ!”+ mi ò sì tíì rí i títí di báyìí.