8 Jèhófà Ọlọ́run wá gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì,+ ní apá ìlà oòrùn; ó sì fi ọkùnrin tó dá+ síbẹ̀. 9 Torí náà, Jèhófà Ọlọ́run mú kí gbogbo igi tó dùn-ún wò, tó sì dára fún oúnjẹ hù látinú ilẹ̀, ó sì mú kí igi ìyè+ hù ní àárín ọgbà náà pẹ̀lú igi ìmọ̀ rere àti búburú.+