18 Nígbà tí Ábúsálómù ṣì wà láàyè, ó ṣe òpó kan, ó sì gbé e nàró fún ara rẹ̀ ní Àfonífojì Ọba,+ torí ó sọ pé: “Mi ò ní ọmọkùnrin tí á máa jẹ́ orúkọ mi lọ.”+ Nítorí náà, ó fi orúkọ ara rẹ̀ pe òpó náà, Ohun Ìrántí Ábúsálómù ni wọ́n sì ń pè é títí di òní yìí.