42 Nígbà tí wọ́n sọ fún Rèbékà ohun tí Ísọ̀ ọmọ rẹ̀ àgbà sọ, ojú ẹsẹ̀ ló ránṣẹ́ pe Jékọ́bù ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àbúrò, ó sì sọ fún un pé: “Wò ó! Ísọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ ń wá bó ṣe máa pa ọ́ kó lè gbẹ̀san. 43 Torí náà, ọmọ mi, ṣe ohun tí mo bá sọ fún ọ. Gbéra, kí o sì sá lọ sọ́dọ̀ Lábánì arákùnrin mi ní Háránì.+