31 Oòrùn wá yọ ní gbàrà tó kọjá Pénúélì, àmọ́ ó ń tiro torí ohun tó ṣe ìbàdí+ rẹ̀. 32 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé títí dòní, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í jẹ iṣan tó wà níbi itan ní oríkèé egungun ìbàdí, torí ó fọwọ́ kan iṣan tó wà níbi itan ní oríkèé egungun ìbàdí Jékọ́bù.