5 O ò ní jẹ́ Ábúrámù* mọ́; orúkọ rẹ yóò di Ábúráhámù,* torí màá mú kí o di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. 6 Màá mú kí o bímọ tó pọ̀ gan-an, màá mú kí o di àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ọba yóò sì tinú rẹ jáde.+
13 Wọ́n wá mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là! Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà,*+ Ọba Ísírẹ́lì!”+