-
Diutarónómì 17:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 “Tí o bá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, tí o gbà á, tí o ti ń gbé ibẹ̀, tí o wá sọ pé, ‘Jẹ́ kí n yan ọba lé ara mi lórí, bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí mi ká,’+ 15 nígbà náà, kí o rí i dájú pé ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn ni kí o fi jọba.+ Àárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ẹni tó máa jọba. O ò gbọ́dọ̀ yan àjèjì, ẹni tí kì í ṣe arákùnrin rẹ ṣe olórí rẹ.
-
-
1 Kíróníkà 1:43-50Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Àwọn ọba tó jẹ ní ilẹ̀ Édómù+ kí ọba kankan tó jẹ lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ nìyí: Bélà ọmọ Béórì; orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dínhábà. 44 Nígbà tí Bélà kú, Jóbábù ọmọ Síírà láti Bósírà+ bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 45 Nígbà tí Jóbábù kú, Húṣámù láti ilẹ̀ àwọn ará Témánì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 46 Nígbà tí Húṣámù kú, Hádádì ọmọ Bédádì, ẹni tó ṣẹ́gun Mídíánì ní agbègbè* Móábù bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Áfítì. 47 Nígbà tí Hádádì kú, Sámúlà láti Másírékà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 48 Nígbà tí Sámúlà kú, Ṣéọ́lù láti Réhóbótì lẹ́gbẹ̀ẹ́ Odò bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 49 Nígbà tí Ṣéọ́lù kú, Baali-hánánì ọmọ Ákíbórì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. 50 Nígbà tí Baali-hánánì kú, Hádádì bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Páù, orúkọ ìyàwó rẹ̀ sì ni Méhétábélì ọmọ Mátírédì, ọmọbìnrin Mésáhábù.
-