-
Ẹ́kísódù 26:15-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 “Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn náà, kí wọ́n wà ní òró.+ 16 Kí gígùn férémù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 17 Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan férémù náà ní ìtẹ̀bọ̀ méjì* lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe gbogbo férémù àgọ́ ìjọsìn náà. 18 Kí o ṣe ogún (20) férémù sí apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn náà, kó dojú kọ gúúsù.
-