-
Ẹ́kísódù 26:36, 37Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
36 Kí o fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ṣe aṣọ* tí ẹ máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà.+ 37 Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe òpó márùn-ún fún aṣọ* náà, kí o sì fi wúrà bo àwọn òpó náà. Kí o fi wúrà ṣe àwọn ìkọ́ wọn, kí o sì fi bàbà ṣe ìtẹ́lẹ̀ márùn-ún tó ní ihò fún wọn.
-