-
Ẹ́kísódù 28:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 “Àwọn aṣọ tí wọ́n á ṣe nìyí: aṣọ ìgbàyà,+ éfódì,+ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá,+ aṣọ tó ní bátànì igun mẹ́rin, láwàní+ àti ọ̀já;+ kí wọ́n ṣe àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kó lè di àlùfáà mi. 5 Àwọn òṣìṣẹ́ tó mọṣẹ́ náà yóò lo wúrà náà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀* tó dáa.
-