ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 28:15-21
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 “Kí o mú kí ẹni tó ń kó iṣẹ́ sí aṣọ ṣe aṣọ ìgbàyà ìdájọ́.+ Kó ṣe é bí éfódì, kí ó lo wúrà, fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa láti fi ṣe é.+ 16 Kí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dọ́gba tí wọ́n bá ṣẹ́ ẹ po sí méjì, kó jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan* ní gígùn àti ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan ní fífẹ̀. 17 Kí o to àwọn òkúta sórí rẹ̀, kí o to òkúta náà ní ìpele mẹ́rin. Kí ìpele àkọ́kọ́ jẹ́ rúbì, tópásì àti émírádì. 18 Kí ìpele kejì jẹ́ tọ́kọ́wásì, sàfáyà àti jásípérì. 19 Kí ìpele kẹta jẹ́ òkúta léṣémù,* ágétì àti ámétísì. 20 Kí ìpele kẹrin jẹ́ kírísóláítì, ónísì àti jéèdì. Kí o lẹ̀ wọ́n mọ́ ìtẹ́lẹ̀ tí o fi wúrà ṣe. 21 Àwọn òkúta náà yóò dúró fún orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì méjìlá (12). Kí o fín orúkọ sára òkúta kọ̀ọ̀kan bí èdìdì, kí orúkọ kọ̀ọ̀kan dúró fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjìlá (12) náà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́