-
Ẹ́kísódù 38:9-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ó wá ṣe àgbàlá.+ Ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tó máa wà ní apá gúúsù àgbàlá náà, níbi tó dojú kọ gúúsù.+ 10 Ó ní ogún (20) òpó àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe, fàdákà ni wọ́n sì fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 11 Bákan náà, ó ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n máa ta sí apá àríwá. Bàbà ni wọ́n fi ṣe ogún (20) òpó wọn àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn. Fàdákà ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.*
-