5 Yàtọ̀ sí ìyẹn, èmi yóò béèrè ẹ̀jẹ̀ yín tó jẹ́ ẹ̀mí yín pa dà. Èmi yóò béèrè lọ́wọ́ gbogbo ohun alààyè; ọwọ́ kálukú ni màá sì ti béèrè ẹ̀mí arákùnrin rẹ̀.+ 6 Ẹnikẹ́ni tó bá ta ẹ̀jẹ̀ èèyàn sílẹ̀, èèyàn ni yóò ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀,+ torí àwòrán Ọlọ́run ni Ó dá èèyàn.+