-
Ẹ́kísódù 10:16-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ni Fáráò bá yára pe Mósè àti Áárónì, ó sì sọ pé: “Mo ti ṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, mo sì ti ṣẹ̀ yín. 17 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ dárí jì mí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo yìí, kí ẹ sì bẹ Jèhófà Ọlọ́run yín pé kó mú ìyọnu ńlá yìí kúrò lórí mi.” 18 Ó* wá kúrò lọ́dọ̀ Fáráò, ó sì bẹ Jèhófà.+ 19 Jèhófà sì mú kí atẹ́gùn náà ṣẹ́rí pa dà, ó wá ń fẹ́ lọ sí ìwọ̀ oòrùn, atẹ́gùn náà sì le gan-an. Ó gbé àwọn eéṣú náà lọ, ó sì gbá wọn sínú Òkun Pupa. Eéṣú kankan ò ṣẹ́ kù ní gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì.
-