-
Jóṣúà 24:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Nígbà tí mo mú àwọn bàbá yín kúrò ní Íjíbítì,+ tí ẹ sì dé òkun, àwọn ará Íjíbítì ń fi àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn agẹṣin lé àwọn bàbá yín títí dé Òkun Pupa.+ 7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà,+ ó wá fi òkùnkùn sáàárín ẹ̀yin àti àwọn ará Íjíbítì, ó mú kí òkun ya wá sórí wọn, ó bò wọ́n mọ́lẹ̀,+ ẹ sì fi ojú ara yín rí ohun tí mo ṣe ní Íjíbítì.+ Ọ̀pọ̀ ọdún* lẹ fi wà ní aginjù.+
-
-
Nehemáyà 9:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 “O rí ìpọ́njú àwọn baba ńlá wa ní Íjíbítì,+ o sì gbọ́ igbe ẹkún wọn ní Òkun Pupa.
-