21 “‘O ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìyàwó ọmọnìkejì rẹ wọ̀ ọ́ lójú.+ O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúkòkòrò ilé ọmọnìkejì rẹ tàbí oko rẹ̀ tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.’+
7 Kí wá ni ká sọ? Ṣé Òfin wá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ká sòótọ́, mi ò bá má ti mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí kì í bá ṣe Òfin.+ Bí àpẹẹrẹ, mi ò bá má mọ ojúkòkòrò ká ní Òfin ò sọ pé: “O ò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò.”+