ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 38:9-15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 Ó wá ṣe àgbàlá.+ Ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀* lílọ́ tó dáa ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tó máa wà ní apá gúúsù àgbàlá náà, níbi tó dojú kọ gúúsù.+ 10 Ó ní ogún (20) òpó àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò tí wọ́n fi bàbà ṣe, fàdákà ni wọ́n sì fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 11 Bákan náà, ó ṣe àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) ìgbọ̀nwọ́ tí wọ́n máa ta sí apá àríwá. Bàbà ni wọ́n fi ṣe ogún (20) òpó wọn àti ogún (20) ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn. Fàdákà ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 12 Àmọ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́ ni àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí apá ìwọ̀ oòrùn. Òpó mẹ́wàá àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá tó ní ihò wà níbẹ̀, fàdákà ni wọ́n sì fi ṣe ìkọ́ àwọn òpó náà àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀.* 13 Fífẹ̀ apá ìlà oòrùn tí oòrùn ti ń yọ jẹ́ àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́. 14 Àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) wà ní ẹ̀gbẹ́ kan, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò. 15 Àwọn aṣọ ìdábùú tó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) sì wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, lápá kejì ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ìtẹ́lẹ̀ mẹ́ta tó ní ihò.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́