ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 39:22-26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Lẹ́yìn náà, ó ṣe aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá sí éfódì náà, ẹni tó ń hun aṣọ fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù ṣe é látòkè délẹ̀.+ 23 Ó yọ ọrùn sí aṣọ àwọ̀lékè náà ní àárín, bí ọrùn ẹ̀wù irin. Ó ṣe ìgbátí sí ọrùn rẹ̀ yí ká, kó má bàa ya. 24 Lẹ́yìn náà, wọ́n fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù àti òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò tí wọ́n lọ́ pọ̀ ṣe pómégíránétì sí etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà. 25 Wọ́n fi ògidì wúrà ṣe àwọn agogo, wọ́n sì fi àwọn agogo náà sáàárín àwọn pómégíránétì yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá náà, láàárín àwọn pómégíránétì; 26 wọ́n to agogo kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan, agogo kan tẹ̀ lé pómégíránétì kan yí ká etí aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.

  • Léfítíkù 8:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Lẹ́yìn náà, ó wọ aṣọ+ fún un, ó de ọ̀já+ mọ́ ọn, ó wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ fún un, ó wọ éfódì+ fún un, ó sì fi àmùrè éfódì tí wọ́n hun pọ̀*+ dè é mọ́ ọn pinpin.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́