-
Ẹ́kísódù 35:30-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Mósè wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ wò ó, Jèhófà ti yan Bẹ́sálẹ́lì ọmọ Úráì ọmọ Húrì látinú ẹ̀yà Júdà.+ 31 Ó ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀, ó fún un ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ nípa onírúurú iṣẹ́ ọnà, 32 kó lè ṣe iṣẹ́ ọnà ayàwòrán, kó lè fi wúrà, fàdákà àti bàbà ṣiṣẹ́, 33 kó lè gé òkúta, kó sì tò ó, kó sì lè fi igi ṣe onírúurú iṣẹ́ ọnà. 34 Ó sì ti fi sínú ọkàn rẹ̀ láti máa kọ́ni, òun àti Òhólíábù+ ọmọ Áhísámákì látinú ẹ̀yà Dánì.
-
-
1 Kíróníkà 2:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Húrì bí Úráì. Úráì bí Bẹ́sálẹ́lì.+
-