-
Ẹ́kísódù 29:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Kí o pa àgbò náà, kí o mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+ 17 Gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, kí o fọ ìfun rẹ̀+ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì to àwọn ègé ẹran náà pẹ̀lú orí rẹ̀. 18 Kí o sun àgbò náà lódindi, jẹ́ kó rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ló jẹ́ sí Jèhófà, olóòórùn dídùn.*+ Ó jẹ́ ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.
-
-
Léfítíkù 8:18-21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Ó mú àgbò tó fẹ́ fi rú ẹbọ sísun náà wá sí tòsí, Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí àgbò náà.+ 19 Lẹ́yìn náà, Mósè pa á, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 20 Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mósè sì mú kí orí àgbò náà, àwọn ègé rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle* rú èéfín. 21 Ó fi omi fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, Mósè sì mú kí odindi àgbò náà rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun tó ní òórùn dídùn* ni. Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ló jẹ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
-
-
Léfítíkù 9:12-14Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Lẹ́yìn náà, ó pa ẹran ẹbọ sísun náà, àwọn ọmọ Áárónì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ fún un, ó sì wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+ 13 Wọ́n kó àwọn ègé ẹran ẹbọ sísun náà àti orí rẹ̀ fún un, ó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ. 14 Ó tún fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì mú kó rú èéfín lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ.
-