-
Léfítíkù 4:8-10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 “‘Lẹ́yìn náà, kó yọ gbogbo ọ̀rá tó wà lára akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, títí kan ọ̀rá tó bo ìfun àti ọ̀rá tó yí ìfun ká 9 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ rẹ̀. 10 Ohun kan náà tó yọ lára akọ màlúù ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ ni kó yọ. Kí àlùfáà sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ ẹbọ sísun.
-
-
1 Sámúẹ́lì 2:16, 17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Nígbà tí ọkùnrin náà bá sọ fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ mú ọ̀rá rú èéfín ná,+ lẹ́yìn ìyẹn, kí o mú ohun tí ọkàn rẹ bá fẹ́.”* Àmọ́ á sọ pé: “Rárá, fún mi báyìí-báyìí; àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, màá mú un tipátipá!” 17 Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ náà wá pọ̀ gan-an níwájú Jèhófà,+ nítorí àwọn ọkùnrin náà hùwà àìlọ́wọ̀ sí ọrẹ Jèhófà.
-