-
Ẹ́kísódù 29:19, 20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
19 “Lẹ́yìn náà, kí o mú àgbò kejì, kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ wọn lé orí àgbò náà.+ 20 Kí o pa àgbò náà, kí o mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àti sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún àwọn ọmọ rẹ̀, kí o tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn, kí o sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.
-