29 “Ohun tí o máa ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́ kí wọ́n lè di àlùfáà mi nìyí: Mú ọmọ akọ màlúù kan, àgbò méjì tí kò ní àbùkù,+ 2 búrẹ́dì aláìwú, búrẹ́dì aláìwú tí wọ́n pò mọ́ òróró, tó rí bí òrùka àti búrẹ́dì aláìwú pẹlẹbẹ tí wọ́n fi òróró pa.+ Ìyẹ̀fun àlìkámà tó kúnná ni kí o fi ṣe wọ́n.