13 Àmọ́ tí ọmọbìnrin àlùfáà bá di opó tàbí tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí kò sì ní ọmọ, tó sì pa dà sí ilé bàbá rẹ̀ bí ìgbà tó wà léwe, ó lè jẹ nínú oúnjẹ bàbá rẹ̀;+ àmọ́ ẹni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i* kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.
11 Ìwọ náà lo tún ni èyí: àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú+ wá pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fífì+ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá. Mo ti fún ìwọ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ pẹ̀lú rẹ, kó jẹ́ ìpín+ yín títí lọ. Gbogbo ẹni tó mọ́ nínú ilé rẹ ló lè jẹ ẹ́.+