-
Léfítíkù 7:1-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “‘Òfin ẹbọ ẹ̀bi+ nìyí: Ohun mímọ́ jù lọ ni. 2 Ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ sísun ni kí wọ́n ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀bi, kí wọ́n sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀+ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+ 3 Kó mú gbogbo ọ̀rá rẹ̀+ wá, pẹ̀lú ìrù ọlọ́ràá, ọ̀rá tó bo ìfun 4 àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá wọn tó wà nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín náà.+
-