4 Ìkankan nínú àwọn ọmọ Áárónì tó bá jẹ́ adẹ́tẹ̀+ tàbí tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ títí ẹni náà yóò fi di mímọ́,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ẹni tí òkú èèyàn* sọ di aláìmọ́+ tàbí ọkùnrin tó ń da àtọ̀+
10 Tí ọkùnrin kan bá di aláìmọ́ torí pé àtọ̀ dà lára rẹ̀ ní òru,+ kó kúrò nínú ibùdó, kó má sì pa dà síbẹ̀. 11 Tó bá di ìrọ̀lẹ́, kó fi omi wẹ̀, tí oòrùn bá sì ti wọ̀, kó pa dà sínú ibùdó.+