Ẹ́kísódù 40:21 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 21 Ó gbé Àpótí náà wá sínú àgọ́ ìjọsìn, ó sì ta aṣọ ìdábùú+ bo ibẹ̀. Ó fi bo ibi tí àpótí Ẹ̀rí náà+ wà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. Hébérù 6:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 A ní ìrètí yìí+ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn,* ó dájú, ó fìdí múlẹ̀, ó sì wọlé sẹ́yìn aṣọ ìdábùú,+ Hébérù 9:3 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 3 Àmọ́ lẹ́yìn aṣọ ìdábùú kejì,+ apá kan wà tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ.+ Hébérù 9:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 àmọ́ àlùfáà àgbà nìkan ló máa ń wọ apá kejì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún,+ kì í wọ ibẹ̀ láìsí ẹ̀jẹ̀,+ èyí tó fi máa ń rúbọ fún ara rẹ̀+ àti fún ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn+ dá láìmọ̀ọ́mọ̀.
21 Ó gbé Àpótí náà wá sínú àgọ́ ìjọsìn, ó sì ta aṣọ ìdábùú+ bo ibẹ̀. Ó fi bo ibi tí àpótí Ẹ̀rí náà+ wà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.
7 àmọ́ àlùfáà àgbà nìkan ló máa ń wọ apá kejì lẹ́ẹ̀kan lọ́dún,+ kì í wọ ibẹ̀ láìsí ẹ̀jẹ̀,+ èyí tó fi máa ń rúbọ fún ara rẹ̀+ àti fún ẹ̀ṣẹ̀ táwọn èèyàn+ dá láìmọ̀ọ́mọ̀.