2 Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín kí ẹ má bàa dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, a ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi,+ ẹni tó jẹ́ olódodo.+ 2 Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ tiwa nìkan, àmọ́ fún gbogbo ayé pẹ̀lú.+