-
Jẹ́nẹ́sísì 19:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Wọ́n ń pe Lọ́ọ̀tì, wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Àwọn ọkùnrin tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí dà? Mú wọn jáde ká lè bá wọn lò pọ̀.”+
-
-
Léfítíkù 20:13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin sùn bí ìgbà tó ń bá obìnrin sùn, ohun ìríra ni àwọn méjèèjì ṣe.+ Ẹ gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn.
-
-
Àwọn Onídàájọ́ 19:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Bí wọ́n ṣe ń gbádùn ara wọn, àwọn ọkùnrin kan tí kò ní láárí nínú ìlú yí ilé náà ká, wọ́n sì ń gbá ilẹ̀kùn, wọ́n ń sọ fún bàbá arúgbó tó ni ilé náà pé: “Mú ọkùnrin tó wá sínú ilé rẹ jáde, ká lè bá a lò pọ̀.”+
-
-
Róòmù 1:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi yọ̀ǹda wọn fún ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tó ń tini lójú,+ nítorí àwọn obìnrin wọn ti yí ìlò ara wọn pa dà sí èyí tó lòdì sí ti ẹ̀dá;+ 27 bákan náà, àwọn ọkùnrin fi ìlò obìnrin* lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì jẹ́ kí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ mú ara wọn gbóná janjan sí ara wọn, ọkùnrin sí ọkùnrin,+ wọ́n ń ṣe ohun ìbàjẹ́, wọ́n sì ń jẹ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìyà* tó yẹ ìṣìnà wọn.+
-
-
1 Kọ́ríńtì 6:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Àbí ẹ ò mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run ni?+ Ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣì yín lọ́nà.* Àwọn oníṣekúṣe,*+ àwọn abọ̀rìṣà,+ àwọn alágbèrè,+ àwọn ọkùnrin tó ń jẹ́ kí ọkùnrin bá wọn lò pọ̀,+ àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀,*+ 10 àwọn olè, àwọn olójúkòkòrò,+ àwọn ọ̀mùtípara,+ àwọn pẹ̀gànpẹ̀gàn* àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+
-