-
Léfítíkù 25:29, 30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 “‘Tí ọkùnrin kan bá ta ilé kan nínú ìlú olódi, kí ẹ̀tọ́ tó ní láti ṣe àtúnrà ṣì wà láti ìgbà tó bá ti tà á títí ọdún yóò fi parí; ó ní ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà+ láàárín ọdún kan gbáko. 30 Àmọ́ tí kò bá rà á pa dà títí ọdún kan fi pé, kí ilé tó wà nínú ìlú olódi náà di ohun ìní ẹni tó rà á títí láé jálẹ̀ àwọn ìran rẹ̀. Kò gbọ́dọ̀ dá a pa dà nígbà Júbílì.
-
-
Léfítíkù 27:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ní ọdún Júbílì, ilẹ̀ náà yóò pa dà di ti ẹni tó tà á fún un, yóò di ti ẹni tó ni ilẹ̀ náà.+
-