16 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, mi ò ní jẹ́ kí oúnjẹ wà ní Jerúsálẹ́mù,+ ṣe ni wọ́n máa wọn búrẹ́dì tí wọ́n fẹ́ jẹ látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní,+ ọkàn wọn ò sì ní balẹ̀. Wọ́n máa wọn omi tí wọ́n fẹ́ mu látinú ìwọ̀nba tí wọ́n ní, ẹ̀rù á sì máa bà wọ́n.+