15 Ọwọ́ ọmọnìkejì rẹ ni kí o ti rà á, wo iye ọdún tó tẹ̀ lé Júbílì, iye ọdún tó bá sì kù láti kórè ni kó fi tà á fún ọ.+ 16 Tí iye ọdún tó ṣẹ́ kù bá pọ̀, ó lè fowó lé iye tó fẹ́ tà á, àmọ́ tí iye ọdún tó kù kò bá pọ̀, kó dín iye tó fẹ́ tà á kù, torí iye irè oko tó máa hù ló fẹ́ tà fún ọ.