ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 12:7, 8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Kí àlùfáà mú un wá síwájú Jèhófà, kó ṣe ètùtù fún obìnrin náà, á sì mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ tó ń dà lára rẹ̀. Èyí ni òfin nípa obìnrin tó bímọ ọkùnrin tàbí obìnrin. 8 Tí agbára rẹ̀ ò bá gbé àgùntàn, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì,+ ọ̀kan fún ẹbọ sísun, ìkejì fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí àlùfáà ṣe ètùtù fún un, obìnrin náà á sì mọ́.’”

  • Léfítíkù 14:21, 22
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 21 “Àmọ́, tó bá jẹ́ aláìní, tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́, kó mú ọmọ àgbò kan láti fi rú ẹbọ ẹ̀bi, kó fi ṣe ọrẹ fífì, kó lè ṣe ètùtù fún ara rẹ̀, pẹ̀lú ìyẹ̀fun tó kúnná, tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà,* tí wọ́n pò mọ́ òróró láti fi ṣe ọrẹ ọkà, òróró tó kún òṣùwọ̀n lọ́ọ̀gì kan, 22 àti ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, èyí tí agbára rẹ̀ bá gbé. Ọ̀kan máa jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì á sì jẹ́ ẹbọ sísun.+

  • Léfítíkù 15:13-15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “‘Tí ohun tó ń dà náà bá dáwọ́ dúró, tí ẹni náà sì wá mọ́ kúrò nínú rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje, lẹ́yìn náà kó di mímọ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, yóò sì di mímọ́.+ 14 Ní ọjọ́ kẹjọ, kó mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé+ méjì, kó wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì kó wọn fún àlùfáà. 15 Kí àlùfáà sì fi wọ́n rúbọ, kó fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kó fi èkejì rú ẹbọ sísun, kí àlùfáà sì ṣe ètùtù fún un níwájú Jèhófà torí ohun tó ń dà jáde lára rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́